Fara Wé Ìgbàgbọ́ Wọn
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù túmọ̀ ìgbàgbọ́ sí “ìfojúsọ́nà pẹ̀lú ìdánilójú fún àwọn ohun tí a ń retí, ìfihàn gbangba gbàǹgbà àwọn ohun gidi bí a kò tilẹ̀ rí wọn.” Ó fi kún un pé, “láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣeé ṣe láti wu [Ọlọ́run] dáadáa.” (Heb. 11:1, 6) Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá láti lo ìgbàgbọ́, kí a kún fún ìgbàgbọ́ lákùn-únwọ́sílẹ̀, kí a sì lépa rẹ̀.—2 Kọr. 4:13; Kol. 2:7; 2 Tim. 2:22.
2 A ní ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ títayọ lọ́lá tí a ròyìn nínú Bíbélì. Ní Hébérù orí 11, Pọ́ọ̀lù dárúkọ ọ̀pọ̀ ẹlẹ́rìí tí wọ́n ṣàṣefihàn ìgbàgbọ́ aláìyẹhùn. Ébẹ́lì, ẹni àkọ́kọ́ tí a ṣekú pa nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀, wà lára àwọn tí a dárúkọ. A dárúkọ Nóà nítorí nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó fi ìbẹ̀rù oníwà-bí-ọlọ́run tí a nílò láti fi gba agbo ilé rẹ̀ là hàn. A gbóríyìn fún Ábúráhámù fún ìgbàgbọ́ àti ìgbọ́ràn rẹ̀. A yin Mósè nítorí nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó ń bá a nìṣó ní fífẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni náà tí a kò lè rí. Àwọn àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ náà pọ̀ púpọ̀ débi tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé àkókò kì yóò tó fún òun bí òún bá ń bá a nìṣó láti ròyìn gbogbo wọn. Ẹ wo bí a ti kún fún ọpẹ́ tó pé a lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun nípa ṣíṣàyẹ̀wò “awọn ìṣe mímọ́ ní ìwà àti àwọn ìṣe ìfọkànsin Ọlọ́run” wọn!—2 Pet. 3:11.
3 Ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù béèrè ìbéèrè náà pé: “Nígbà tí Ọmọkùnrin ènìyàn bá dé, òun yóò ha bá ìgbàgbọ́ ní ilẹ̀ ayé ní ti gidi bí?” (Luk. 18:8) Ó dára, nígbà náà, a ha ní àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ ní ti gidi láàárín wa lónìí bí? A ha rí àwọn ọkùnrin àti obìnrin, tọmọdé tàgbà, tí ń fi ìgbàgbọ́ aláìyẹhùn hàn nínú Jèhófà bí ó ti jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní àwọn àkókò tí a kọ Bíbélì?
4 Àwọn Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Ti Òde Òní: A lè rí àwọn àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ títayọ lọ́lá yíká wa! Ìgbàgbọ́ àwọn alábòójútó tí wọ́n ń mú ipò iwájú láàárín wa yẹ láti fara wé. (Heb. 13:7) Ṣùgbọ́n kì í ṣe àwọn wọ̀nyí nìkan ni wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú ìgbàgbọ́. Àwọn adúróṣinṣin tí ń fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́ sìn Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún, lọ́pọ̀ ìgbà lábẹ́ àwọn àyíká ipò líle koko, ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìjọ kọ̀ọ̀kan.
5 A gbọ́dọ̀ yin àwọn arábìnrin wa olùṣòtítọ́, tí wọ́n ti fara da àtakò fún ọ̀pọ̀ ọdún láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkọ aṣòdì síni. Àwọn òbí anìkàntọ́mọ ti ní láti kojú ìpènijà dídánìkan tọ́ àwọn ọmọ. Àwọn opó ọlọ́jọ́ lórí wà láàárín wa, tí wọn kì í pa àwọn ìgbòkègbodò ìjọ jẹ, àní bí wọn kò tilẹ̀ ní ìdílé láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (Fi wé Luk. 2:37.) Ìgbàgbọ́ àwọn tí ń fara da àwọn ìṣòro ìlera lemọ́lemọ́ máa ń wú wa lórí. Ọ̀pọ̀ ń bá a nìṣó láti máa fi ìdúróṣinṣin ṣiṣẹ́ sìn, bí wọ́n tilẹ̀ ní ohun tí ó káwọ́ wọn rọ láti tẹ́rí gba àfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí wà tí wọ́n ti fi ìgboyà lo ìgbàgbọ́ láìka àtakò ní ilé ẹ̀kọ́ sí. Ìfọkànsìn oníwà-bí-ọlọ́run wa ń lágbára sí i bí a ti ń wo àwọn aṣáájú ọ̀nà olùṣòtítọ́ tí wọ́n ń forí tì í láti ọdún dé ọdún lójú àwọn ìṣòro tí kò ṣeé fẹnu sọ. Gan-an gẹ́gẹ́ bíi Pọ́ọ̀lù, àkókò kì yóò tó fún wa bí a bá gbìyànjú láti sọ gbogbo ìrírí tí ó wà nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba àti àwọn ìṣe ìgbàgbọ́ tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọ̀nyí ti ṣe!
6 Àpẹẹrẹ àwọn olùṣòtítọ́ wọ̀nyí ń fún wa ní ìtùnú àti ìṣírí. (1 Tẹs. 3:7, 8) A ṣe dáradára láti fara wé ìgbàgbọ́ wọn nítorí “àwọn tí ń ṣe rere ni dídùn inú [Jèhófà].”—Òwe 12:22.