Mímú Ẹ̀jẹ́ Wa Ṣẹ Lójoojúmọ́
1 A sún onísáàmù náà, Dáfídì, láti sọ fún Jèhófà pé: “Èmi óò máa kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ láéláé, kí èmi kí ó lè máa san ẹ̀jẹ́ mi ní ojoojúmọ́.” (Sm. 61:8) Dáfídì mọ̀ pé jíjẹ́jẹ̀ẹ́ jẹ́ ọ̀ràn àfínnúfíndọ̀ṣe pátápátá. Ṣùgbọ́n, ó tún lóye pé, bí òún bá jẹ́jẹ̀ẹ́, ó di ọ̀ranyàn fún òun láti mú un ṣẹ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ó yin Jèhófà fún àǹfààní tí ó ní láti mú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ lójoojúmọ́.
2 Nígbà tí a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a fi tinútinú jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ṣe ìfẹ rẹ̀. A sẹ́ níní ara wa, a sì sọ ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà di ìlépa wa àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé. (Luk. 9:23) Nípa báyìí, àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ san ẹ̀jẹ́ wa lójoojúmọ́. (Onw. 5:4-6) Ìpolongo ní gbangba tí a ṣe nígbà tí a ṣe batisí inú omi, gbọ́dọ̀ fara hàn nínú ọ̀nà tí a ń gbà gbé ìgbésí ayé, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé “ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.” (Rom. 10:10) Èyí kan wíwàásù ìhìn rere. (Heb. 13:15) Àyíká ipò ẹnì kọ̀ọ̀kán yàtọ̀ síra gidigidi, ṣùgbọ́n, lójoojúmọ́, gbogbo wá lè fún ìjẹ́pàtàki ṣíṣàjọpín ìhìn rere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ní àfiyèsí àkànṣe.
3 Wá Àyè Láti Wàásù Lójoojúmọ́: Ṣíṣàjọpín ìhìn rere pẹ̀lú ẹlòmíràn jẹ́ ìrírí aláyọ̀. Láti lè ṣe èyí lójoojúmọ́, a ní láti wá àyè láti wàásù nígbàkigbà tí àyíká ipò wá bá yọ̀ǹda fún un. Àwọn tí wọ́n ti lo àtinúdá láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà ní ibi iṣẹ́ tàbí ní ilé ẹ̀kọ́ àti fún àwọn aládùúgbò tàbí àwọn mìíràn tí wọ́n ṣalábàápàdé lójoojúmọ́, ti gbádùn ọ̀pọ̀ ìrírí aláyọ̀. Àní kíkọ lẹ́tà tàbí lílo tẹlifóònù pàápàá lè jẹ́ ọ̀nà ìgbà jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn. Lílo gbogbo ọ̀nà wọ̀nyí àti wíwá àyè déédéé láti jẹ́rìí ní ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà àti ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò lè ṣamọ̀nà sí àkànṣe ìdùnnú tí ń wá láti inú dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. Bẹ́ẹ̀ ni, ó lè ṣeé ṣe fún wa lójoojúmọ́ láti wá àyè láti wàásù.
4 Arábìnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí í ka Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́, nígbà ìsinmi ráńpẹ́ níbi iṣẹ́. Ó ké sí òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan láti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọjọ́ náà pẹ̀lu rẹ̀, kò sì pẹ́ tí ìyẹ́n fi ṣamọ̀nà sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú obìnrin náà. Wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lójoojúmọ́, ní ọjọ́ márùn-ún láàárín ọ̀sẹ̀. Òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn mìíràn kíyè sí ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́ wọn. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí arákùnrin aláìṣiṣẹ́mọ́. Bí ìtara arábìnrin náà ti sún un, ó kàn sí alàgbà kan láti lè di ẹni tí a mú sọjí padà. Arábìnrin yìí ní agbára ìdarí rere lórí ẹni méjì míràn, nítorí tí ó ṣiṣẹ́ lóri mímú ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ṣẹ lójoojúmọ́.
5 Tí ọkàn-àyà tí ó kún fún ìmọrírì fún gbogbo ohun rere tí Jèhófà ti ṣe fún wa bá ń sún wa ṣiṣẹ́, mímú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ dé ibi tí agbára wa mọ, lójoojúmọ́, yóò mú ìdùnnú àti ìtẹ́lọ́rùn wá fún wa. Gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà, a lè polongo pé: “Èmi óò yìn ọ́, Olúwa Ọlọ́run mi, tinútinú mi gbogbo: èmi óò sì máa fi ògo fún orúkọ rẹ títí láé.”—Sm. 86:12.