A San Èrè fún Ìṣòtítọ́
1 Ní Hébérù 11:6, a sọ fún wa pé Ọlọ́run “di olùsẹ̀san fún àwọn wọnnì tí ń fi taratara wá a.” Ọ̀nà kan tí ó gbà ń san èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùfọkànsìn tí wọ́n ti jẹ́ ‘olùṣòtítọ́ nínú ìwọ̀nba ohun díẹ̀’ ni nípa ‘yíyàn wọ́n sípò lórí ohun púpọ̀.’ (Mát. 25:23) Lédè míràn, Jèhófà sábà máa ń san èrè fún iṣẹ́ aláápọn nípa fífún àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀ olùṣòtítọ́ ní àfikún ẹrù iṣẹ́ ìsìn.
2 A san èrè fún ìṣòtítọ́ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nípa yíyàn án sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí ó mú kí ó lọ sí àwọn ìlú àti abúlé tí ó wà ní Europe àti Éṣíà Kékeré. (1 Tím. 1:12) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ gba ìsapá púpọ̀, Pọ́ọ̀lù fọwọ́ daindain mú àǹfààní tí ó rí gbà. (Róòmù 11:13; Kól. 1:25) Ó fi ìmọrírì rẹ̀ àtọkànwá hàn nípa wíwá àǹfààní taratara láti wàásù. Nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ onítara, ó fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ hàn kedere nípa iṣẹ́. Àpẹẹrẹ rẹ̀ ń sún wa láti máa ṣìkẹ́ àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí a ní.
3 Jèhófà Ti Fún Wa Ní Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kan: Báwo ni a ṣe ń fi ojú ìwòye kan náà hàn nípa àǹfààní iṣẹ́ ìsìn yí bí Pọ́ọ̀lù ti fi hàn? A ń wá ọ̀nà láti mú kí ipa tí a ń kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pọ̀ sí i. A ń lo gbogbo àǹfààní tí ó bá ṣí sílẹ̀ láti jẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà àti láti ilé dé ilé. A ń pa dà sọ́dọ̀ gbogbo ẹni tí kò bá sí nílé, a sì ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ gbogbo ẹni tí ó bá fi ọkàn ìfẹ́ hàn. A sì ń pa àdéhùn tí a bá ṣe mọ́ láti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
4 Ní ti iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, Pọ́ọ̀lù gbà wá nímọ̀ràn pé: ‘Ẹ wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú.’ (2 Tím. 4:2) Ohun kan tí ó jẹ́ kánjúkánjú ń béèrè fún àfiyèsí lọ́gán. A ha ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ́nà tí ó fi ìjẹ́kánjúkánjú hàn, ní fífún un ní ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa bí? Fún àpẹẹrẹ, a kì yóò fẹ́ kí àwọn ìgbòkègbodò eré ìtura wa àti àwọn ìlépa ti ara ẹni mìíràn ní òpin ọ̀sẹ̀ ṣèdíwọ́ fún àkókò tí ó yẹ kí a yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Níwọ̀n bí ó ti dá wa lójú pé òpin ètò ìgbékalẹ̀ nǹkan yìí ń yára sún mọ́lé, ó dá wa lójú pẹ̀lú pé wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà ni iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí a lè ṣe.
5 A ń fi ìṣòtítọ́ wa sí Ọlọ́run hàn nípa jíjẹ́ tí a jẹ́ adúróṣinṣin àti aláìyẹhùn sí i àti nípa dídúró tí a dúró gangan nínú iṣẹ́ tí òun ti yàn fún wa. Ẹ jẹ́ kí a ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, kí Jèhófà baà lè san èrè fún ìṣòtítọ́ wa lọ́nà púpọ̀ jaburata.