ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/07 ojú ìwé 1
  • Bá A Ṣe Lè Túbọ̀ Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bá A Ṣe Lè Túbọ̀ Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Láṣeyanjú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́kùnrin, Ǹjẹ́ Ẹ Ṣe Tán Láti Di Ìránṣẹ́ Tàbí Alàgbà?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àwọn Ọ̀nà Tí O Lè Gbà Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Ẹ Kọ́ Àwọn Míì Kí Wọ́n Lè Tóótun Fún Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 9/07 ojú ìwé 1

Bá A Ṣe Lè Túbọ̀ Tẹra Mọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa

1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni kí wọ́n máa ṣe, àti pé kí wọ́n “tẹra mọ́ títúbọ̀ ṣe é.” (1 Tẹs. 4:1) Kí ni gbólóhùn yìí túmọ̀ sí? Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ máa wá bá a ṣe lè túbọ̀ tẹra mọ́ bá a ṣe ń ṣe sí nínú ìgbòkègbodò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, ká máa sapá ní gbogbo ìgbà láti “ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ [wa] ní kíkún.”—2 Tím. 4:5.

2 Ohun Tó Ń Sún Wa Ṣe É: Wíwù tó ń wù wá láti sin Ẹlẹ́dàá wa tẹ́rùntẹ́rùn ló ń mú ká túbọ̀ máa tẹra mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. A fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run ká sì wá bá a ṣe lè fi kún ojúṣe wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ohun tó lè mú kọ́wọ́ wa tẹ àfojúsùn yìí ni ètò tó gún régé tá a fi òótọ́ inú ṣe.—Sm. 1:1, 2; Fílí. 4:6; Héb. 10:24, 25.

3 Àmọ́ ká tó lè túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, dandan ni ká jẹ́ ọ̀làwọ́, ìyẹn ni pé ká lè yọ̀ǹda ara wa láti ṣèrànwọ́ fáwọn ẹlòmíì. Kò ní ṣòroó ṣe bá a bá lè máa fi tàdúràtàdúrà ṣàṣàrò lórí àpẹẹrẹ àtàtà tí Jésù fi lélẹ̀. (Mát. 20:28) Jálẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ńṣe ló máa ń láyọ̀ nítorí pé ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fáwọn ẹlòmíì. (Ìṣe 20:35) Àwa náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa jíjẹ́ kí ọ̀ràn àwọn ẹlòmíì jẹ wá lógún, ká sì wà lójúfò láti máa lo àǹfààní tó bá yọ láti túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.—Aísá. 6:8.

4 Ojúṣe Òbí: Látìgbà táwọn ọmọ bá ti wà ní kékeré ló ti yẹ ká kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn ẹlòmíì àti bí wọ́n ṣe lè máa túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Àwọn ọmọdé máa ń kíyè sí ọwọ́ táwọn òbí wọn àtàwọn ẹ̀gbọ́n wọn fi mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti bí wọn kì í ṣeé jáfara láti túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Láti kékeré ni arákùnrin kan báyìí ti máa ń kíyè sí ọwọ́ tí bàbá ìyá rẹ̀ fi ń mú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ, èyí sì mú kí ọ̀dọ́kùnrin yìí pinnu láti túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Bó ṣe ń kíyè sí ọwọ́ tí bàbá ìyá rẹ̀ fi mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti bí bàbá náà ṣe máa ń láyọ̀ mú kóun náà wá bó ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn ará. Ó ti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ báyìí.

5 À Ń Wá Àwọn Arákùnrin: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń nàgà . . . , iṣẹ́ àtàtà ni ó ń fẹ́.” (1 Tím. 3:1) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi gbólóhùn yìí gba àwọn arákùnrin níyànjú láti sapá kí wọ́n lè yẹ lẹ́ni táá máa bójú tó àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ètò Jèhófà. Kò dìgbà tí wọ́n bá ní òye iṣẹ́ àrà ọ̀tọ̀ kan. Ohun àkọ́kọ́ tó pọn dandan kí irú arákùnrin bẹ́ẹ̀ ṣe ni pé kó kọ́kọ́ wá Ìjọba Ọlọ́run, kó sì máa fìtara ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́. (Mát. 6:33; 2 Tím. 4:5) Kó sapá láti máa fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn ẹlòmíràn.

6 Kárí Ayé: Jèhófà túbọ̀ ń mú kí iṣẹ́ ìkójọ náà yára kánkán. (Aísá. 60:22) Nítorí náà, àkókò tá a wà yìí ló yẹ káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù túbọ̀ jara mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ìròyìn iṣẹ́ ìsìn tọdún 2006 fi hàn pé àwọn tó ṣèrìbọmi jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé méjìdínláàádọ́ta àti ọ̀ọ́dúnrún lé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [248,327]. Ìyẹn dà bíi ká sọ pé okòó-dín-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [680] làwọn èèyàn tó ń ṣèrìbọmi lójoojúmọ́! Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa tẹra mọ́ títúbọ̀ ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún sí i.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́