Ẹ̀yin Ọ̀dọ́kùnrin, Ǹjẹ́ Ẹ Ṣe Tán Láti Di Ìránṣẹ́ Tàbí Alàgbà?
1. Ìgbà wo ló yẹ kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìtọ́ni tó wà nínú 1 Tímótì 3:1 sílò?
1 Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń fẹ́ láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà nínú ìjọ “iṣẹ́ àtàtà ni ó ń fẹ́.” (1 Tím. 3:1) Bíbélì fún àwọn arákùnrin níṣìírí pé kí wọ́n máa sapá kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà nínú ìjọ. Àmọ́, ṣé ó dìgbà tó o bá dàgbà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í sapá láti kúnjú ìwọ̀n fún irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀? Láti kékeré ló ti yẹ kó máa wù ọ́ láti máa ṣiṣẹ́ nínú ìjọ. Wàá lè fi hàn pé o fẹ́ kí àwọn alàgbà dá ẹ lẹ́kọ̀ọ́, kó o lè kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nígbà tó o bá dàgbà tó. (1 Tím. 3:10) Tó o bá jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin tó ti ṣèrìbọmi, kí làwọn nǹkan tó o lè ṣe láti fi hàn pé o ti múra tán láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà nínú ìjọ?
2. Báwo lo ṣe lè ní ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni, kó o sì máa fi irú ẹ̀mí bẹ́ẹ̀ hàn?
2 Máa Yọ̀ǹda Ara Rẹ: Rántí pé iṣẹ́ àtàtà lò ń fẹ́ láti ṣe, kì í ṣe oyè lo fẹ́ jẹ. Torí náà, jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti ran àwọn ará lọ́wọ́. Ọ̀nà kan tó o sì lè gbà ṣe ìyẹn ni pé kó o máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. (Mát. 20:28; Jòh. 4:6, 7; 13:4, 5) Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ àwọn ará. (1 Kọ́r. 10:24) Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o lè ṣe nǹkan kan láti ṣèrànwọ́ fún àwọn àgbàlagbà tó wà nínú ìjọ tàbí àwọn tí ara wọn kò fi bẹ́ẹ̀ le? Ṣé o máa ń yọ̀ǹda ara rẹ láti gé koríko ní àyíká Gbọ̀ngàn Ìjọba, láti gbálẹ̀ tàbí láti ṣe àwọn àtúnṣe míì ní Gbọ̀ngàn Ìjọba? Tí ẹni tó níṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run kò bá wá, ǹjẹ́ o máa ń yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe iṣẹ́ náà? Tó o bá ń yọ̀ǹda ara rẹ láti ran àwọn míì lọ́wọ́, wàá túbọ̀ máa láyọ̀.—Ìṣe 20:35.
3. Kí nìdí tó fi yẹ kó o jẹ́ ẹni tẹ̀mí? Báwo lo ṣe lè di ẹni tẹ̀mí?
3 Jẹ́ Ẹni Tẹ̀mí: Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí àwọn tá a yàn sípò nínú ìjọ jẹ́ ẹni tẹ̀mí ju pé kí wọ́n ní àwọn ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ tàbí ẹ̀bùn àbínibí lọ. Ẹni tẹ̀mí máa ń sapá láti fi ojú tí Jèhófà àti Jésù fi ń wo nǹkan wò ó. (1 Kọ́r. 2:15, 16) Ó máa ń fi “èso ti ẹ̀mí” ṣèwà hù. (Gál. 5:22, 23) Ó máa ń fi ìtara wàásù. Ire Ìjọba Ọlọ́run ló sì máa ń gbájú mọ́. (Mát. 6:33) O lè di ẹni tẹ̀mí tó o bá ń ya àkókò sọ́tọ̀ láti máa dá kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Èyí gba pé kó o máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó o máa ka gbogbo ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó ń jáde, kó o máa múra ìpàdé sílẹ̀, kó o sì máa wá sípàdé déédéé. (Sm. 1:1, 2; Héb. 10:24, 25) Nígbà tí Tímótì wà ní ọ̀dọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà á níyànjú pé kó túbọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó ní: “Máa fiyè sí . . . ẹ̀kọ́ rẹ.” (1 Tím. 4:15, 16) Torí náà, rí i pé ò ń múra iṣẹ́ tí wọ́n bá fún ọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run sílẹ̀ dáadáa. Máa múra òde ẹ̀rí sílẹ̀, kó o sì máa lọ déédéé. Rí i pé o ní àfojúsùn tẹ̀mí, kó o sì máa sapá kọ́wọ́ rẹ lè tẹ̀ ẹ́. Lára àwọn ohun tó o lè fi ṣe àfojúsùn rẹ ni láti di aṣáájú-ọ̀nà, láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n. Tó o bá jẹ́ ẹni tẹ̀mí, wàá lè “sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.”—2 Tím. 2:22.
4. Kí nìdí tó fi yẹ kó o jẹ́ olóòótọ́ àti ẹni tó ṣeé fọkàn tán?
4 Jẹ́ Olóòótọ́ àti Ẹni Tó Ṣeé Fọkàn Tán: Àwọn arákùnrin tí wọ́n yàn pé kí wọ́n máa pín oúnjẹ fún àwọn ará ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní jẹ́ àwọn tí “a jẹ́rìí gbè.” Èyí fi hàn pé wọ́n ṣeé fọkàn tán, wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́. Torí náà, àwọn àpọ́sítélì fọkàn tán wọn pé wọ́n á ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́. Èyí sì jẹ́ kí àwọn àpọ́sítélì lè ráyè bójú tó àwọn iṣẹ́ pàtàkì míì. (Ìṣe 6:1-4) Tí wọ́n bá yan iṣẹ́ fún ọ nínú ìjọ, rí i pé o fi tọkàntara ṣe é. Tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Nóà tí Ọlọ́run ní kó kan ọkọ̀ áàkì, gbogbo ìtọ́ni tí Ọlọ́run fún un ló tẹ̀ lé. (Jẹ́n. 6:22) Jèhófà mọyì ẹni tó bá jẹ́ olóòótọ́. Jíjẹ́ olóòótọ́ sì máa fi hàn pé o dàgbà nípa tẹ̀mí.—1 Kọ́r. 4:2; wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní “Ẹ Máa Dá Wọn Lẹ́kọ̀ọ́.”
5. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin sapá kí wọ́n lè di ìránṣẹ́ tàbí alàgbà nínú ìjọ?
5 Àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ pé Jèhófà ń yára kánkán láti mú ọ̀pọ̀ èèyàn wá sínú ètò rẹ̀. (Aís. 60:22) Bí àpẹẹrẹ, ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta lé rúgba [250,000] èèyàn ló ń ṣèrìbọmi, ní ìpíndọ́gba, lọ́dọọdún. Torí bí ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun ṣe ń wá sínú òtítọ́, a nílò àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n, tí wọ́n sì jẹ́ ẹni tẹ̀mí láti bójú tó àwọn iṣẹ́ nínú ìjọ. Lásìkò yìí, a ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Jèhófà ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. (1 Kọ́r. 15:58) Ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin, ǹjẹ́ ẹ ṣe tán láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà nínú ìjọ? Tẹ́ ẹ bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ àtàtà ni ẹ̀ ń fẹ́ láti ṣe!
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 2]
Torí bí ọ̀pọ̀ àwọn ẹni tuntun ṣe ń wá sínú òtítọ́, a nílò àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n, tí wọ́n sì jẹ́ ẹni tẹ̀mí láti bójú tó àwọn iṣẹ́ nínú ìjọ
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Ẹ Máa Dá Wọn Lẹ́kọ̀ọ́
Àǹfààní wà nínú kí àwọn alàgbà máa yan iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó kúnjú ìwọ̀n, kí wọ́n sì máa dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn ìpàdé lọ́jọ́ kan, alábòójútó àyíká jókòó sórí pèpéle, ó ń bá akéde kan sọ̀rọ̀. Àmọ́, ó tajú kán rí ọmọdékùnrin kan tó dúró sí tòsí, ló bá béèrè pé ṣé ó fẹ́ rí òun ni. Ọmọdékùnrin náà dá a lóhùn pé iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún òun ni láti máa gbá orí pèpéle lẹ́yìn ìpàdé, àwọn òbí òun sì ti fẹ́ máa lọ, àmọ́ òun kò fẹ́ lọ sílé láìṣe iṣẹ́ yẹn. Inú alábòójútó àyíká yẹn dùn, ó sì kúrò níbẹ̀ kí ọmọ náà lè ráyè ṣe iṣẹ́ yẹn. Lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Àwọn alàgbà ìjọ yẹn sábà máa ń yan iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tó bá kúnjú ìwọ̀n láti fi dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Abájọ tí wọ́n fi máa ń dábàá pé kí ètò Ọlọ́run yan àwọn ọ̀dọ́ inú ìjọ wọn sípò ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, nígbà tí mo bá bẹ ìjọ wọn wò.”