ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/06 ojú ìwé 1
  • A Fẹ́ Kó O Ṣèrànwọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Fẹ́ Kó O Ṣèrànwọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìránṣẹ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ń Ṣe Ìjọ Láǹfààní
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ẹ̀yin Arákùnrin, Ẹ Fúnrúgbìn Nípa Tẹ̀mí, Kẹ́ Ẹ Sì Máa Wá Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ẹ̀yin Ọ̀dọ́kùnrin, Ǹjẹ́ Ẹ Ṣe Tán Láti Di Ìránṣẹ́ Tàbí Alàgbà?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Ẹ Kọ́ Àwọn Míì Kí Wọ́n Lè Tóótun Fún Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 1/06 ojú ìwé 1

A Fẹ́ Kó O Ṣèrànwọ́

1 “Ẹ ṣeun púpọ̀ fún gbogbo ohun tẹ́ ẹ̀ ń ṣe fún wa. Ipa tó ń ní lórí wa ò kéré.” Irú ọ̀rọ̀ tá a máa ń sọ gan-an rèé tá a bá fẹ́ fi hàn pé a mọrírì àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́. Bí ètò Ọlọ́run ṣe ń gbòòrò sí i, ṣe la túbọ̀ ń fẹ́ àwọn ọkùnrin tó tó fa iṣẹ́ lé lọ́wọ́, tá máa sìn nínú nǹkan bí ọ̀kẹ́ márùn-ún ìjọ tó wà káàkiri ayé. Bó o bá ti ṣèrìbọmi, à ń fẹ́ kíwọ náà ṣèrànwọ́.

2 Bó O Ṣe Lè “Nàgà fún” Un: Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ sí àfikún iṣẹ́ ìsìn yìí? (1 Tím. 3:1) Olórí ohun tó o lè ṣe ni pé kó o jẹ́ ẹni tó ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nínú gbogbo ọ̀nà tó ò ń gbà gbé ìgbésí ayé rẹ. (1 Tím. 4:12; Títù 2:6-8; 1 Pét. 5:3) Máa kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìwàásù kó o sì máa ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti máa ṣe bẹ́ẹ̀. (2 Tím. 4:5) Máa fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni jẹ ọ́ lógún. (Róòmù 12:13) Máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run taápọn taápọn kó o sì kọ́ láti ní “ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́” tó dáa. (Títù 1:9; 1 Tím. 4:13) Máa múra sí iṣẹ́ táwọn alàgbà bá gbé lé ọ lọ́wọ́. (1 Tím. 3:10) Bó o bá jẹ́ olórí ìdílé, ‘bójú tó agbo ilé rẹ lọ́nà tó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.’—1 Tím. 3:4, 5, 12.

3 Ó gba iṣẹ́ àṣekára àti ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ kéèyàn tó lè sìn bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. (1 Tím. 5:17) Nítorí náà, ohun tó yẹ kó wà lọ́kàn rẹ ni bí wàá ṣe máa sin àwọn ará tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀, tó o bá fẹ́ fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ yìí. (Mát. 20:25-28; Jòh. 13:3-5, 12-17) Ṣàṣàrò lórí àwọn ànímọ́ rere tí Tímótì ní kó o sì ṣiṣẹ́ lórí bí ìwọ náà ṣe lè ní wọn. (Fílí. 2:20-22) Jẹ́ kí ìwà tìẹ náà ròyìn rẹ dáadáa bíi ti Tímótì. (Ìṣe 16:1, 2) Bó o bá ń kọ́ àwọn ànímọ́ rere tó yẹ kó o ní láti lè bójú tó àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn púpọ̀ sí i, tó o sì ń fi àwọn ìmọ̀ràn tí wọ́n bá ń fún ọ sílò, “ìlọsíwájú rẹ [á] fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tím. 4:15.

4 Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Láti Ṣèrànwọ́: Àwọn ọmọ yín lè bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ bí wọ́n á ṣe ṣèrànwọ́ láti kékeré. Ẹ kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe máa fetí sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nípàdé, bí wọ́n á ṣe máa wàásù àti bí wọ́n á ṣe máa hùwà rere nígbà tí wọ́n bá wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba àti nílé ẹ̀kọ́. Ẹ kọ́ wọn bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíràn, bíi ṣíṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́, ríran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ àti ṣíṣe àwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ káwọn náà rí ayọ̀ tó wà nínú fífúnni. (Ìṣe 20:35) Bẹ́ ẹ bá ń kọ́ wọn nírú àwọn ẹ̀kọ́ yìí, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di aṣáájú-ọ̀nà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà lọ́jọ́ iwájú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́