Àwọn Ọ̀nà Tí O Lè Gbà Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Gbòòrò Sí I
1 Ní ohun tó ju ogójì ọdún sẹ́yìn, àpilẹ̀kọ kan táa pe àkọlé rẹ̀ ní “Eyiti O Nfi Gbogbo Agbara Ṣe Ha Dara To Bi?” jáde nínú Ile-Iṣọ Na, January 15, 1955. Ó fìfẹ́ ṣàlàyé bó ṣe lè rọrùn fún àwọn ènìyàn Jèhófà láti mú kí ìsapá ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ sunwọ̀n sí i kí wọ́n lè mú kí ìgbòkègbodò Ìjọba náà tí wọ́n ń ṣe pọ̀ sí i. Ìmọ̀ràn rere yẹn tún wúlò lónìí, bí a ti ń gbìyànjú láti túbọ̀ ṣe dáadáa sí i.
2 Gbogbo iṣẹ́ ìsìn wa ni a gbọ́dọ̀ máa sún wa ṣe nítorí àṣẹ títóbi jù lọ tí ó sọ pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30) A ń fi gbogbo ìfẹ́ wa hàn sí Jèhófà nípa lílo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àǹfààní tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa láti mú kí iṣẹ́ Ìjọba náà tẹ̀ síwájú. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀nà tó tẹ̀ lé e yìí tóo lè gbà mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i.
3 Ṣe Ojúṣe Rẹ: Àwọn arákùnrin tó ti ṣèyàsímímọ́ lè sakun láti tóótun gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, lẹ́yìn náà kí wọ́n tẹ̀ síwájú láti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà. Àwọn àpilẹ̀kọ náà, “Iwọ Ha Ńnàgà Bí?” àti “Iwọ Ha Tóótun láti Ṣiṣẹ́sìn Bí?,” nínú Ilé-Ìṣọ́nà September 1, 1990, ti sún ọ̀pọ̀ arákùnrin ṣiṣẹ́ láti mú ara wọn wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ. Béèrè lọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ rẹ fún àwọn àbá pàtó lórí bí o ṣe lè nàgà kí o sì tóótun.
4 A ń ké sí àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ àpọ́n láti ronú jinlẹ̀ ní ti bíbéèrè fún lílọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. O lè dojúlùmọ̀ ilé ẹ̀kọ́ yìí nípa kíka àwọn ìtọ́ka lábẹ́ ìsọ̀rí “Ministerial Training School” (Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́) nínú àwọn ìwé Watch Tower Publications Index tọdún 1986 sí 1995, 1996, àti 1997. O ha rí i pé ‘ilẹ̀kùn ńlá ti ìgbòkègbodò’ ṣí sílẹ̀ níwájú rẹ bí? (1 Kọ́r. 16:9a) Ọ̀pọ̀ arákùnrin tí wọ́n wọnú rẹ̀ kò ronú kan gbogbo àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tí ń bẹ lẹ́yìn rẹ̀ rí. Lónìí, wọ́n ń gbádùn sísìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí nínú pápá gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe, míṣọ́nnárì, tàbí alábòójútó àyíká.
5 Nàgà fún Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún: Ó yẹ káwọn ọ̀dọ́ tí ń gboyè jáde nílé ẹ̀kọ́, àwọn ìyàwó ilé, àti ẹnikẹ́ni tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ gbé ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà yẹ̀ wò dáadáa. Kódà ó ṣeé ṣe fún àwọn ará tí ń ṣòwò àti àwọn tí ń ṣiṣẹ́ ìjọba láti ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé, pàápàá nísinsìnyí tí wákàtí tí a ń béèrè ti dín kù. Ṣàtúnyẹ̀wò àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 1998, lẹ́yìn náà, bá àwọn aṣáájú ọ̀nà tí àyíká ipò wọn nínú ìgbésí ayé jọ tìrẹ sọ̀rọ̀. Ó lè jẹ́ pé a óò sún ọ láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i nípa ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà, bí àwọn náà ti ń ṣe. (1 Kọ́r. 11:1) Yóò ha ṣeé ṣe fún ọ láti mú kí ìgbòkègbodò rẹ gbòòrò sí i dé àádọ́rin wákàtí lóṣù kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé bí?
6 Ní báyìí, ó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ń sìn ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àti ní ilé Bẹ́tẹ́lì kárí ayé. Ojú ìwé 116 sí 118 nínú ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa, jíròrò ohun táa ń béèrè láti wọ irú iṣẹ́ ìsìn bẹ́ẹ̀. Èé ṣe tí o kò fi kà á kí o sì wò ó bóyá o lè tóótun fún iṣẹ́ ìsìn aláìlẹ́gbẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì?
7 Sìn Níbi Tí Àìní Gbé Pọ̀ Jù: Ṣé ibi tí a ti máa ń ṣe ìpínlẹ̀ déédéé tàbí ibi tí ọ̀pọ̀ ará wà láti ṣe iṣẹ́ náà lo ń gbé? Ṣé o ti ronú nípa mímú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i nípa ṣíṣí lọ sí ibi tí àìní gbé pọ̀? Ó lè jẹ́ ìgbèríko kan tó wà nítòsí níbi tí a ti túbọ̀ ń fẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ sí i ló yẹ kí o ṣí lọ. (Mát. 9:37, 38) Kò yẹ kóo fìkánjú ṣe èyí. Ó yẹ kí o ronú nípa rẹ̀ tàdúràtàdúrà. (Lúùkù 14:28-30) Bá àwọn alàgbà àti alábòójútó àyíká jíròrò ipò rẹ. Wọn yóò bá ọ ronú pọ̀ bóyá ó bọ́gbọ́n mu kí o ṣí lọ nísinsìnyí tàbí kí o múra láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bí o bá fẹ́ láti kọ̀wé sí Society fún ìmọ̀ràn ní ti ibi tí o lè ṣí lọ, kí lẹ́tà tí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ rẹ fọwọ́ sí bá lẹ́tà rẹ rìn.
8 Mú Kí Iṣẹ́ Ìsìn Rẹ Sunwọ̀n Sí I: Ó ṣeé ṣe kí gbogbo wa lè nípìn-ín púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ nípa mímú kí iṣẹ́ ìsìn pápá wa sunwọ̀n sí i. Ǹjẹ́ o máa ń lọ́wọ́ nínú gbogbo apá iṣẹ́ náà, títí kan wíwàásù láti ilé dé ilé, ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà, àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Bí o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́, ǹjẹ́ o lè mú kí bí o ṣe ń kọ́ni sunwọ̀n sí i? Ó dára pé kí o ṣàtúnyẹ̀wò àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996 fún àwọn àbá tí o lè lò láti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ níṣìírí ṣíṣe ìyàsímímọ́ àti batisí.
9 Ìjíròrò kíkúnrẹ́rẹ́ nípa àwọn ọ̀nà tí a lè gbà mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò kó sì sunwọ̀n sí i wà ní orí kẹsàn-án ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa. Dájúdájú, gbogbo wa ló yẹ kó fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun táa bá lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kò yẹ kí o ronú jinlẹ̀ gidigidi lórí àwọn góńgó rẹ nípa tẹ̀mí? Ṣe ohun tí 1 Tímótì 4:15 dámọ̀ràn pé: “Máa fẹ̀sọ̀ ronú lórí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá, kí ìlọsíwájú rẹ lè fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”