Ṣé O Fẹ́ Ṣe Púpọ̀ Sí I?
1 Jésù fi Ìjọba náà wé ìṣúra tí kò ṣeé díye lé. (Mát. 13:44-46) Wíwàásù ìhìn Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìṣúra iyebíye pẹ̀lú. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí ló yẹ kó gba ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa, àní bí kíkópa ní kíkún nínú rẹ̀ yóò bá gba pé ká yááfì àwọn ohun kan. (Mát. 6:19-21) Ṣé ó wù ọ́ pé kí o túbọ̀ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run?
2 Ronú Nípa Àwọn Ohun Pàtàkì Wọ̀nyí: Àwọn nǹkan mélòó kan wà tó pọndandan kí á tó lè mú kí ipa tí olúkúlùkù wa ń kó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ túbọ̀ pọ̀ sí i, àwọn ni: (1) pípinnu láti fi àwọn ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò kìíní ní ìgbésí ayé (Mát. 6:33); (2) lílo ìgbàgbọ́ àti gbígbáralé Jèhófà (2 Kọ́r. 4:1, 7); (3) wíwá ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà àtọkànwá nígbà gbogbo (Lúùkù 11:8-10); (4) ṣíṣiṣẹ́ lórí àdúrà wa àti ṣíṣe àwọn nǹkan tó wà níbàámu pẹ̀lú àdúrà wa.—Ják. 2:14, 17.
3 Àwọn Ọ̀nà Táa Lè Gbà Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Gbòòrò Sí I: Gbogbo wa lè fi lílo àkókò púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣooṣù ṣe ohun pàtàkì tí a óò máa lépa. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o ti ronú nípa lílo gbogbo àǹfààní tóo bá ní láti jẹ́rìí lọ́nà tí kò jẹ́ bí àṣà, láti ṣakitiyan kí bí o ṣe ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀ túbọ̀ múná dóko, kí bí o ṣe ń ṣe ìpadàbẹ̀wò túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i, kí o sì sapá láti máa bá àwọn èèyàn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń tẹ̀ síwájú nínú ilé wọn? Ǹjẹ́ o lè ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú ọ̀nà déédéé tàbí kí o lọ sìn níbi tí wọ́n túbọ̀ ń fẹ́ ìrànwọ́? Bí o bá jẹ́ arákùnrin tó ti ṣe ìrìbọmi, ǹjẹ́ o lè sapá kí o bàa tóótun láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà? (1 Tím. 3:1, 10) Ǹjẹ́ o lè mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i nípa wíwá àǹfààní láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì tàbí láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́?—Lúùkù 10:2.
4 Wọ́n fún arákùnrin kan tó máa ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀, tó sì máa ń lo àkókò púpọ̀ nídìí eré ìdárayá níṣìírí láti di aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ó sì ṣàtúnṣe ọ̀ràn ara rẹ̀ láti wọnú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Lẹ́yìn ìyẹn, ó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, èyí sì ṣèrànwọ́ láti múra rẹ̀ fún iṣẹ́ táa yàn fún un báyìí, ìyẹn iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Inú rẹ̀ dùn pé òun kọbi ara sí ìṣírí tí wọ́n fún òun yẹn, ó sì dá a lójú pé ìpinnu tí òun ṣe láti ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà ló mú kí òun túbọ̀ láyọ̀.
5 Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá yọ̀ǹda ara wọn. (Aís. 6:8) Má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dí ọ lọ́wọ́ tí o kò fi ní mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i kí o sì gbádùn ìtẹ́lọ́rùn àti ìtura ńláǹlà tó ń wá látinú rẹ̀.