Àpótí Ìbéèrè
◼ Báwo làwọn òbí ṣe gbọ́dọ̀ kíyè sára nígbà táwọn ọmọ wọn kéékèèké bá ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá?
Lọ́nà yíyẹ, àwọn Kristẹni òbí máa ń mú àwọn ọmọ wọn lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, wọ́n sì máa ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ láti ṣàjọpín ìhìn rere Ìjọba náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tí wọ́n bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó yẹ kí wọ́n máa kíyè sí àwọn ọmọ wọn kéékèèké nítorí ewu tó lè ṣẹlẹ̀ sí wọn ní ìpínlẹ̀ wọn, kódà ní àwọn àdúgbò “tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu” pàápàá. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ túbọ̀ ń di ẹni tí a ń hùwà ipá sí tí a sì ń fìyà jẹ nítorí ojúkòkòrò àti ìwà ìbàjẹ́ takọtabo tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní “àwọn àkókò lílekoko” tí a ń gbé nínú rẹ̀ wọ̀nyí. (2 Tím. 3:1-5) Ó yẹ káwọn òbí kíyè sára dáadáa láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn kéékèèké lọ́wọ́ àwọn tí yóò fẹ́ fi wọ́n ṣèjẹ. Kí ni wọ́n lè ṣe?
Lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, Bíbélì gbani nímọ̀ràn pé ka kíyè sára ká sì máa wo ẹ̀yìn ọ̀ràn láti lè yẹra fún ewu. (Òwe 22:3; Mát. 10:16) Kì í ṣe ìlànà la ń gbé kalẹ̀ níhìn-ín, ṣùgbọ́n ó bọ́gbọ́n mu pé kí òbí kan tàbí àgbàlagbà mìíràn wà pẹ̀lú ọmọdé kan nígbà tó bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá. Bí ọ̀dọ́ méjì, tí wọ́n ṣeé fọkàn tẹ̀, tí wọ́n jẹ́ akéde bá jọ ń ṣiṣẹ́, ó dára pé kí òbí kan tàbí àgbàlagbà mìíràn máa wà níbi tí ojú rẹ̀ ti lè tó wọn nígbà gbogbo. Àmọ́ ṣáá o, bí ọmọ kan ṣe ń dàgbà sí i, tó sì ń fi hàn pé òun tóó dá ìpinnu ṣe, àwọn òbí lè pinnu bóyá ọmọ náà kò fi bẹ́ẹ̀ nílò àbójútó òbí ní tààràtà mọ́.—Wo Àpótí Ìbéèrè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1992 pẹ̀lú.
Ó bọ́gbọ́n mu pẹ̀lú pé ká fọwọ́ tó ṣe pàtàkì mú ọ̀ràn ààbò nígbà tí a bá ń rìnrìn àjò nípasẹ̀ ohun ìrìnnà tàbí nígbà tí a bá ń gbafẹ́ kiri. Ṣíṣọ́ra lọ́nà yíyẹ sábà máa ń dènà jàǹbá àti ìnira tí ń mú ìbànújẹ́ báni nítorí ìrora, owó ìtọ́jú ìṣègùn, àti owó ìtanràn tí òfin tàbí ọ̀ràn ilé ẹjọ́ ń béèrè.
Ó dára kí àwọn ọ̀dọ́ “máa yin orúkọ Jèhófà.” (Sm. 148:12, 13) Ọ̀rọ̀ ẹnú wọn tí ń gbádùn mọ́ni àti ìwà rere wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń wú àwọn ẹlòmíràn lórí, ó sì ń bọlá fún Jèhófà. Ẹ̀yin òbí, ní gbogbo ọ̀nà, ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti máa nípìn-ín déédéé nínú pípòkìkí ìhìn rere náà bí ẹ̀yin pẹ̀lú ti ń wà lójúfò nígbà gbogbo láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ewu èyíkéyìí tó lè ṣẹlẹ̀!