Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run
◼ Albania: Góńgó tuntun nínú iye akéde tí ó jẹ́ 1,556 tí wọ́n ròyìn ní oṣù January dúró fún ìbísí ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún ju ìpíndọ́gba tọdún tó kọjá.
◼ Belau: Àròpọ̀ iye akéde tó jẹ́ 73 lóṣù December jẹ́ ìbísí ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún ju ìpíndọ́gba tọdún tó kọjá, ó sì jẹ́ ìbísí ìpín méjìlélógún nínú ọgọ́rùn-ún ju ti oṣù December ọdún tó kọjá.
◼ Kánádà: A yan ọ̀tàlénírínwó [460] aṣáájú ọ̀nà déédéé láti bẹ̀rẹ̀ ní January 1, 1999.
◼ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà: Society yan ìgbìmọ̀ olùpèsè ìrànwọ́ lákòókò jàǹbá láti ṣàtúnṣe àwọn nǹkan tí ìjì bàjẹ́ ní ìhà gúúsù Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Èyí kan ìkún omi ní Texas àti àwọn nǹkan tí Ìjì Líle Georges bàjẹ́ ní àwọn erékùṣù Florida Keys. Ọ̀nà tí Society gbà ṣètò láti ran àwọn ara lọ́wọ́ àti ọ̀nà tí a gbà ṣe iṣẹ́ ìrànwọ́ náà ya àwọn aládùúgbò lẹ́nu.