Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run
◼ Armenia: Ìròyìn oṣù December fi hàn pé àwọn akéde 4,741 lo wákàtí mẹ́rìndínlógún ní ìpíndọ́gba lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Góńgó tuntun yìí nínú iye akéde jẹ́ ìbísí ìpín mẹ́tàdínlógún nínú ọgọ́rùn-ún ju ìpíndọ́gba tọdún tó kọjá.
◼ Chile: Inú wọ́n dùn láti gbọ́ nípa wákàtí tuntun tí a ń béèrè lọ́wọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà, góńgó wọn tó ju ti ìgbàkígbà rí lọ ti 4,351 àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé tó ròyìn ní oṣù January ló sì fi èyí hàn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn 5,175 ròyìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, iye tó tí ì pọ̀ gidigidi jù lọ nìyẹn nínú ọdún iṣẹ́ ìsìn yìí.
◼ Ukraine: Nínú àwọn 100,129 akéde tó ròyìn ní oṣù January, ìpín méjìlá nínú ìpín ọgọ́rùn-ún wọn ló wà nínú irú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kan. Ukraine dé góńgó 5,516 aṣáájú ọ̀nà déédéé—góńgó mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n tẹ̀ léra—àwọn 6,468 akéde ní àfikún sì ròyìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.