Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní May dé July: Fífi àdìpọ̀ ìwé tí a béèrè fún lọ́dọ̀ Society lọni lọ́nà àkànṣe, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàlàyé nínú lẹ́tà wa ti March 1, 1999. Àdìpọ̀ ìwé mẹ́rin fún ₦60. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kíyè sí i pé àtúnṣe lèyí jẹ́ sí ohun tí a ṣèfilọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February, March, àti April. August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? Àwọn ìwé pẹlẹbẹ Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Our Problems—Who Will Help Us Solve Them?, àti Will There Ever Be a World Without War? ni a lè fi lọni nígbà tó bá yẹ.
◼ Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtẹ̀jáde ti June 1, 1999, a óò máa tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde lédèe Tiv lẹ́ẹ̀kan lóṣù. Ní àfikún sí i, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtẹ̀jáde ti June 1999, a óò máa tẹ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa jáde lédèe Tiv. Kí àwọn ìjọ tó bá ń fẹ́ láti béèrè fún ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ lédèe Tiv béèrè fún wọn nísinsìnyí, kí wọ́n lo fọ́ọ̀mù M-202.