Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti 1999
1 Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi wà nínú aginjù, Jèhófà fún Mósè nítọ̀ọ́ni pé kí ó fi fàdákà ṣe kàkàkí méjì. Bó bá jẹ́ pé kàkàkí kan la fun, a jẹ́ pé àwọn olóyè inú àwọn ẹ̀yà ìdílé ni yóò kóra jọ sẹ́nu àbáwọlé àgọ́ ìpàdé. Bí a bá fun kàkàkí méjèèjì, ìyẹn yóò sọ fún gbogbo àpéjọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n kóra jọ. (Núm. 10:1-4) Lónìí, inú wa kò ha ń dùn nígbà tí a bá gbọ́ ìkéde, bíi ti fífun kàkàkí, tó ń mú kí a kóra jọ sí àwọn àpéjọpọ̀ wa ọdọọdún bí? Ní àwọn àpéjọpọ̀ wa, a máa ń gba àwọn ìtọ́ni àti ìtọ́sọ́nà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti àwọn aṣojú tí ó yàn. Èyí ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa dúró ṣinṣin nìṣó nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run. Ǹjẹ́ inú wa kì í dùn láti rí ẹgbẹẹgbẹ̀rún—bóyá ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá—àwọn ẹlẹgbẹ́ wa tí wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ olùjọsìn, tí wọ́n fi ìfẹ́ kóra jọpọ̀ ní àlàáfíà? Ó dájú pé inú wa máa ń dùn!—Sm. 122:1, 7, 8.
2 Láti October 1998 dé January 1999, a ṣe àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́” tí àròpọ̀ wọn jẹ́ ọgọ́rùn-ún ó lé mẹ́fà ní ìlú méjìlélógún jákèjádò Nàìjíríà. Ìbákẹ́gbẹ́ alárinrin pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa àti onírúurú apá fífanimọ́ra ti ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọpọ̀ náà, ní pàtàkì, àwọn ìrírí pápá àti àwọn ìròyìn nípa ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní àwọn ilẹ̀ mìíràn fún gbogbo wa níṣìírí, ó sì gbé wa ró. Bí a óò ṣe máa kóra jọpọ̀ fún àpéjọpọ̀ àgbègbè tọdún 1999, a óò tún láǹfààní láti gbádùn ẹgbẹ́ àwọn ará ṣíṣeyebíye, a óò sì tún láǹfààní láti dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìṣọ̀kan tó ti fún wa.
3 Bí a ṣe ń múra sílẹ̀ fún Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti 1999, a fẹ́ láti ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìsọfúnni kan tí ẹ óò nílò láti rí ilé ibùwọ̀ gbà ní àpéjọpọ̀ náà. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yín lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ yóò fi hàn pé ẹ̀yin lẹ́nì kọ̀ọ̀kan mọrírì gbogbo ètò tí a ṣe nítorí yín.
4 Ìtọ́ni fún Gbígba Ilé Ibùwọ̀: A óò sakun láti pèsè iye àwọn fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Ibùwọ̀ tó pọ̀ tó fún ìjọ kọ̀ọ̀kan. Kí akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Ibùwọ̀ kọ̀ọ̀kan tí a fi sílẹ̀ la kọ ọ̀rọ̀ kún lọ́nà tó yẹ. MÁ ṢE kọ kìkì iye àwọn akéde tí wọ́n nílò ilé ibùwọ̀, irú bí “50 akéde,” sínú àlàfo tó yẹ ká kọ orúkọ àwọn wọ̀nyí sí. Gbogbo ìsọfúnni náà ni kí a kọ nigín-nigín lọ́nà tó ṣeé kà. Jọ̀wọ́ rí i dájú pé o pèsè kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni ní ti orúkọ, ọjọ́ orí, bóyá ọkùnrin tàbí obìnrin, àti bóyá ẹni náà tí ń béèrè fún ilé ibùwọ̀ jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tàbí akéde ìjọ. Fi àwọn ọmọ kún àkọsílẹ̀ náà. Ní ìgbà kan rí, kìkì orúkọ àwọn àgbàlagbà làwọn ìjọ kan kọ sílẹ̀. Èyí mú kó ṣòro láti ṣètò ilé ibùwọ̀ tí ó tó. Bí ẹ bá nílò àyè sí i ju èyí tí a pèsè lórí fọ́ọ̀mù náà, ẹ lo àfikún abala ìwé. Bí orúkọ tó ju ti ẹnì kan lọ bá wà lórí fọ́ọ̀mù náà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ipò ìbátan tó wà láàárín àwọn tí ń béèrè ilé ibùwọ̀ hàn ní àlàfo ìlà tó yẹ. Kí akọ̀wé ìjọ rí i dájú pé a kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Ibùwọ̀ lọ́nà pípéye ṣáájú kó tó fi ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Ibùwọ̀ àpéjọpọ̀.
5 Lọ́dọọdún, a máa ń rọ àwọn ará láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Ibùwọ̀ àpéjọpọ̀. Ó kéré tán, ohun méjì la máa ń ṣàṣeparí rẹ̀ nípa kíkọbi ara sí ìtọ́sọ́nà yìí:
6 A ń dín àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní ìnáwó kù: Nígbà tí a bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìṣètò Society, ó máa ń dín àwọn ará wa ní owó ilé kù. Dípò kí àṣẹ́kù owó wa máa bọ́ sápò àwọn onílé, a lè lò ó lọ́nà tó sàn jù láti ṣètìlẹ́yìn fún ìdílé àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa àti fún iṣẹ́ wa kárí ayé. Àní bí àwa fúnra wa bá tilẹ̀ lè gba àwọn ilé ibùwọ̀ tí owó wọn wọ́n pàápàá, ó yẹ ká ṣètìlẹ́yìn fún ìsapá Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Ibùwọ̀. Ẹ̀mí àníyàn fún àwọn ẹlòmíràn yìí ni a ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú 1 Jòhánù 3:17, òun sì ni ìlànà tó wà lẹ́yìn 1 Kọ́ríńtì 10:24.
7 A ń ṣègbọràn sí àwọn ìtọ́sọ́nà Society: Kókó yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olórí àníyàn wa. Hébérù 13:17 sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba, nítorí wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn yín bí àwọn tí yóò ṣe ìjíhìn; kí wọ́n lè ṣe èyí pẹ̀lú ìdùnnú, kì í sì í ṣe pẹ̀lú ìmí ẹ̀dùn, nítorí èyí yóò ṣe ìpalára fún yín.” Bí àwọn arákùnrin wa ti ń ṣe ọ̀pọ̀ ètò fún àpéjọpọ̀ àgbègbè wa, a fẹ́ kí wọ́n nímọ̀lára pé a tì wọ́n lẹ́yìn ní kíkún. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kìkì fún ọjọ́ méjì tàbí mẹ́ta lọ́dọọdún la máa ń béèrè ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa lórí ọ̀ràn yìí, ọ̀nà dáradára kan ló jẹ́ láti ti ìsapá wọn lẹ́yìn. Àní bí yíyàn wa bá yàtọ̀, àpẹẹrẹ rere wa, tí àwọn arákùnrin wa àti ayé ń wò, ń gbé ẹ̀mí ìfẹ́, ìṣọ̀kan, àti ìtìlẹ́yìn lárugẹ.—Fílí. 2:1-4.
8 Àwọn Àkànṣe Àìní: Ìpèsè yìí wà fún kìkì àwọn tó nílò ìrànwọ́ àkànṣe látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn láti ṣe àwọn ìwéwèé fún àpéjọpọ̀ wọn, ní pàtàkì ètò ilé ibùwọ̀. Wọ́n tún lè nílò ìrànwọ́ láwọn ọ̀nà mìíràn, èyí tó sinmi lórí àyíká ipò olúkúlùkù wọn. Kìkì àwọn akéde àti aṣáájú ọ̀nà tí wọ́n jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, títí kan àwọn ọmọ wọn tí wọ́n mọ̀wàáhù, tí wọ́n ní àkànṣe àìní tí Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ sì fọwọ́ sí nìkan ni wọ́n tóótun fún ìrànwọ́ lábẹ́ ètò Àkànṣe Àìní. Àwọn ètò mìíràn láti tọ́jú àwọn tó ní àkànṣe àìní ni kí ìjọ tí wọ́n ń bá ṣe ìpàdé pọ̀ bójú tó dípò gbígbé iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe yìí karí àjọ tí ń ṣàbójútó àpéjọpọ̀. Àwọn alàgbà àti àwọn mìíràn tí wọ́n mọ̀ nípa àyíká ipò ẹni náà lè fi ìfẹ́ nawọ́ ìrànlọ́wọ́. Èyí sábà máa ń béèrè pé kí àwọn akéde gbé àìní àwọn tí wọ́n wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, àwọn àgbàlagbà, àwọn aláìlera, àti bóyá àwọn mìíràn, yẹ̀ wò. Àwọn akéde lè nawọ́ ìrànwọ́ nípa gbígbé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ dání pẹ̀lú wọn tàbí nípa bíbójútó àìní wọn láwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ mìíràn.—Ják. 2:15-17; 1 Jòh. 3:17, 18.
9 Àmọ́ ṣáá o, Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Ibùwọ̀ yóò sakun láti pèsè àwọn yàrá ibùwọ̀ tó bójú mu fáwọn akéde tí wọ́n ní àkànṣe àìní bí àwọn tó wà nínú ìjọ kò bá lè ṣèrànwọ́ fún wọn. Àwọn akéde wọ̀nyí lè bá akọ̀wé ìjọ jíròrò ipò wọn. Kí akọ̀wé bá Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ sọ̀rọ̀ láti mọ̀ bó bá ṣeé ṣe fún ìjọ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹni wọ̀nyí láti bójú tó yàrá ibùwọ̀ tiwọn. Bí ìjọ kò bá lè ṣètìlẹ́yìn tí a nílò, akọ̀wé lè fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Ibùwọ̀, lórí èyí tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ náà, “ÀKÀNṢE ÀÌNÍ” sí lókè gàdàgbà, ní ojú ìwé àkọ́kọ́. Kìkì àwọn tí wọ́n ní àkànṣe àìní ni kó kọ ọ̀rọ̀ kún inú fọ́ọ̀mù tí a sàmì sí lọ́nà àkànṣe yìí. Ẹni tó nílò ìrànlọ́wọ́ náà ni kó kọ ọ̀rọ̀ kún un. Kí ó dá a padà fún akọ̀wé, tí yóò rí sí i pé a kọ ọ̀rọ̀ kún un, pé ó péye, tí yóò sì rí ẹ̀rí àrídájú nípa àwọn àyíká ipò tó mú ẹni náà tóótun fún irú ìgbéyẹ̀wò bẹ́ẹ̀. Akọ̀wé ní láti ṢÀLÀYÉ KÚLẸ̀KÚLẸ̀ nípa àwọn àyíká ipò náà sínú àlàfo tó wà ní òdì kejì fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo èyí la ní láti ṣe tipẹ́tipẹ́ ṣáájú àpéjọpọ̀ náà. Lẹ́yìn náà ni akọ̀wé yóò fi fọ́ọ̀mù náà ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Ibùwọ̀. Ẹni tó nílò ìrànlọ́wọ́ náà ni a óò sọ fún ní tààràtà nípa ilé ibùwọ̀ náà.
10 Àwọn tí wọ́n ní àkànṣe àìní KÒ GBỌ́DỌ̀ lọ béèrè fún yàrá nígbà tí wọ́n bá dé àpéjọpọ̀, nítorí pé Ẹ̀ka Tí Ń Bójú Tó Ilé Ibùwọ̀ gbọ́dọ̀ rí ẹ̀rí àrídájú láti ọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọ.
11 Ọ̀pọ̀ ti sọ pé àwọn mọrírì ètò tí a máa ń ṣe fún ilé ibùwọ̀ nígbà àpéjọpọ̀. Ṣé ìwọ náà kún fún ìmoore fún ọ̀pọ̀ ètò tí a ń ṣe nítorí rẹ? Inú Society dùn láti máa pèsè àwọn ilé ibùwọ̀ tí ń tuni lára, tí kò sì wọ́nwó nígbà àpéjọpọ̀, tí ń mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo wa láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn àǹfààní tẹ̀mí tí àpéjọpọ̀ àti ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní.
12 Lílọ sí Àpéjọpọ̀ Mìíràn: Ìjọ kọ̀ọ̀kan la yàn sí àpéjọpọ̀ tó sún mọ́ ọn jù lọ. Bí a ti gbekarí iye àwọn akéde tí a yàn sí àpéjọpọ̀ kọ̀ọ̀kan, Society díwọ̀n iye ènìyàn tí yóò pésẹ̀ láti lè ṣètò fún ìjókòó, ilé ibùwọ̀, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, tí ó tó. Ṣùgbọ́n, bí o bá ní ìdí rere láti lọ sí àpéjọpọ̀ kan tó yàtọ̀ sí èyí tí a yàn ọ́ sí, tí o sì nílò ilé ibùwọ̀, akọ̀wé ìjọ lè fún ọ ní ẹ̀dà kan fọ́ọ̀mù Ìbéèrè fún Ilé Ibùwọ̀. O lè kọ ọ̀rọ̀ kún un, kí o sì jẹ́ kí akọ̀wé fọwọ́ sí i, kí o tó fi ránṣẹ́ sí àpéjọpọ̀ tí o fẹ́ láti lọ.
13 Èdè Adití: A óò ṣètò kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin títóótun túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà ní àwọn àpéjọpọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí: Ọ̀tà 2, November 5-7; Kàdúná 3, November 19-21; Ùlì 7, December 10-12; àti Ùbogò 9, December 17-19, 1999. Àwọn adití ní gbogbo ìjọ ní Nàìjíríà la fún níṣìírí pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wéwèé láti lọ sí ọ̀kan nínú àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí, ó kéré tán. Kí àwọn alàgbà wádìí dáadáa lọ́wọ́ adití kọ̀ọ̀kan tó wà nínú ìjọ wọn tó bá mọ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà láti rí i dájú pé wọ́n mọ̀ nípa ìṣètò yìí kí wọ́n sì lè pinnu bóyá ìrànwọ́ wà tí a gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè lọ.
14 Àwọn àpéjọpọ̀ wọ̀nyí nìkan ni yóò ní ibi tí a ṣètò lákànṣe fún àwọn adití tí a óò fi èdè àwọn adití túmọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fún. A kò ní ṣètò títúmọ̀ lédè àwọn adití ní àpéjọpọ̀ mìíràn èyíkéyìí. Bí adití kan bá bá ẹni tí ń túmọ̀ èdè adití lọ sí àpéjọpọ̀ mìíràn, a gbà pé kí olùtúmọ̀ túmọ̀ fún adití náà nìkan kí àwọn méjèèjì jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn, kì í ṣe pé kó máa túmọ̀ níwájú ẹni náà tàbí níwájú àwùjọ kan.
15 Máa Tọ́jú Owó fún Àpéjọpọ̀ Náà: Ní àfikún sáwọn ìṣètò yòókù, ÌSINSÌNYÍ làkókò láti bẹ̀rẹ̀ sí tọ́jú owó fún àpéjọpọ̀ àgbègbè. Ibi tí àwọn kan ń gbé jìnnà díẹ̀ sí ibi tí wọn yóò ti ṣe àpéjọpọ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn kan ní ìdílé ńlá. Fún àwọn wọ̀nyí àti fún gbogbo wa, a ń fẹ́ owó fún ṣíṣètọrẹ, ọkọ̀, oúnjẹ nígbà àpéjọpọ̀, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, títí kan àwọn ìtẹ̀jáde tuntun, àti àwọn ohun mìíràn tí a kò ronú tẹ́lẹ̀. Ó yẹ káwọn tí wọ́n ní ìdílé ńlá wéwèé ṣáájú kí wọ́n sì tọ́jú owó tí ó tó kí gbogbo ìdílé lè lọ sí àpéjọpọ̀ náà. Ọ̀nà kan tó gbéṣẹ́ lè jẹ́ nípa fífojú díwọ̀n àròpọ̀ iye owó tí a nílò. Ó lọ́gbọ́n nínú láti ṣírò pé owó nǹkan lè ròkè nígbà tí o bá ń fojú díwọ̀n ìnáwó náà. Fi àròpọ̀ iye oṣù tó wà láàárín ìsinsìnyí àti déètì àpéjọpọ̀ àgbègbè yín pín iye owó tí o fojú díwọ̀n. Iye owó tí o ní láti máa fi pa mọ́ lóṣooṣù nìyí. Lóṣooṣù, sọ ọ́ di dandan láti kọ́kọ́ yọ iye owó yìí sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí owó àpéjọpọ̀. O lè fi èyí pa mọ́ sínú àpótí kékeré kan tàbí sínú àpò ìwé. Síbẹ̀, o tún lè pín iye owó tó yẹ kí o máa fi pa mọ́ lóṣooṣù sí ọ̀nà mẹ́rin kí o sì máa tọ́jú rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí o má ṣe dúró dìgbà tí àpéjọpọ̀ bá ku oṣù kan tàbí méjì kí o tó máa gbìyànjú láti kówó jọ fún ìrìn àjò ọdọọdún tí a máa ń lọ déédéé yìí.—Òwe 21:5.
16 Ṣe Ohun Gbogbo fún Ògo Ọlọ́run: Ó ń fúnni níṣìírí láti gbọ́ nípa ìyìn tí a ń fí fún orúkọ Jèhófà nítorí ìwà rere àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní àwọn àpéjọpọ̀. Nígbà tó ń sọ nípa bí àwọn alápèéjọpọ̀ ṣe hùwà lọ́nà ẹ̀yẹ, ẹnì kan tí ń wò wọ́n kọ̀wé pé: “Mo gbádùn ìkórajọ náà. N kò tí ì rí ìsìn kan bí èyí rí. Bí ìkórajọ yìí ṣe tóbi tó, kò sọ́lọ́pàá, kò síjà, ẹ̀ka sísọnù àti ríríhe sì tún wà pẹ̀lú.” Òṣìṣẹ́ kan ní ọ̀kan lára ilé tí a fi àwọn ará wa wọ̀ sí nígbà àpéjọpọ̀ kan sọ pé: “Àwọn alápèéjọpọ̀ yín ni àwọn èèyàn tó dára jù lọ táa ní níhìn-ín.” Òmíràn sọ pé: ‘A fẹ́ràn láti máa gba àwọn èèyàn yín sílé. Gbogbo wọn ló mẹ̀tọ́mọ̀wà.’ Àwọn gbólóhùn wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí rere látọ̀dọ̀ àwọn ara ìta. Orúkọ rere táa ti jèrè ń fògo fún Jèhófà, ó sì ń jẹ́ kó máa fi wá yangàn.—1 Tẹs. 4:12; 1 Pét. 2:12.
17 Ṣùgbọ́n, a tún rí àwọn ìsọfúnni kan tí kò dára gbà nípa àwọn ọmọdé àtàgbàlagbà tí ń rìn gbéregbère káàkiri lákòókò ìtòlẹ́sẹẹsẹ láti àwọn àpéjọpọ̀ kan. Àwọn kan jókòó sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ láti tẹ́tí sí ohùn orin. A rí àwọn kan tí ń kúrò ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ lákòókò ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí wọ́n sì lọ sí hòtẹ́ẹ̀lì àti ilé ọtí. Àwọn mìíràn á lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan tí wọ́n ti ṣètò, wọn a sì máa tàkúrọ̀sọ, wọ́n á tún máa sọ̀tàn. Àwọn kan lọ sílé lẹ́yìn ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀ ọjọ́ Sunday. A kò fẹ́ kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ tún wáyé láwọn àpéjọpọ̀ tọdún yìí. A rọ gbogbo wa pé ká jọ̀wọ́ lo ìkóra-ẹni-níjàánu. A tún ń rán àwọn òbí létí pé kí wọ́n tọ́jú àwọn ọmọ wọn. Bí o bá jẹ́ ẹni tí kò láya tàbí lọ́kọ, tàbí lọ́nà èyíkéyìí, bí o bá lè ran àwọn tí wọ́n ní ọmọ púpọ̀ lọ́wọ́, jọ̀wọ́ ṣe bẹ́ẹ̀.—Gál. 6:2.
18 Kí gbogbo àwọn tó bá pésẹ̀ sí àwọn àpéjọpọ̀ wa mọ̀ pé ibi ìjọsìn làwọ́n wà. Kò sí ẹnikẹ́ni tó gbọ́dọ̀ lo àkókò náà fún iṣẹ́ ajé. Ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ-Ojiṣẹ Wa sọ lójú ìwé 134, ìpínrọ̀ 3 pé: “Kikiyesi lati pa awọn ọpa-idiwọn ododo Ọlọrun mọ́ yoo daabobo wa kuro ninu jíjọlá-anfaani ibakẹgbẹpọ oniṣakoso Ọlọrun fun ṣiṣe àgbàtẹrùn awọn ire okòwò ti ara-ẹni tabi ti awọn ẹlomiran. Ete ibakẹgbẹpọ wa pẹlu awọn ẹlomiran ní awọn ipade Kristian . . . ati nigba tí a bá nlọ si awọn àpéjọ ayika ati awọn àpéjọpọ̀ nla jẹ eyi tí a yasọtọ gédégbé fun jijọsin Jehofah, bíbọ́ ara wa yó lori tabili ti ẹmi ati gbigbadun ajumọṣepaṣipaarọ iṣiri. (Rome 1:11, 12; Heb. 10:24, 25)” Nítorí náà, ó lòdì láti lo àǹfààní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ ìṣàkóso Ọlọ́run fún títa àwọn nǹkan àti ṣíṣiṣẹ́ fún èrè owó ní àwọn àpéjọpọ̀. Èyí tún kan yíya fọ́tò. Kò sí ẹni tó gbọ́dọ̀ polówó iṣẹ́ fọ́tò rẹ̀ ní àpéjọpọ̀ (irú bíi nípa lílẹ káàdì tí ń polówó iṣẹ́ fọ́tò rẹ̀ máyà) bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ máa wá ẹní tó fẹ́ ya fọ́tò kiri níbẹ̀.
19 A fún ọ níṣìírí láti ṣètò nísinsìnyí láti pésẹ̀ sí gbogbo ọjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run” ti 1999. Àwa àti ìwọ ń fojú sọ́nà láti gbọ́ “ohùn igbe ìdùnnú àti ìdúpẹ́” nípa tẹ̀mí látẹnu àwọn tí ń jọ́sìn Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ṣọ̀kan. (Sm. 42:4) Kí Jèhófà bù kún gbogbo ètò tí a ń ṣe fún mímú kí a máa sunwọ̀n sí i nípa tẹ̀mí!
[Àkíyèsí fún Ẹgbẹ́ Àwọn Alàgbà: Bí ẹ bá ti rí àkìbọnú yìí gbà, ẹ jọ̀wọ́, ẹ ṣèfilọ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tó tẹ̀ lé e nípa ibi tí Society yàn pé kí ìjọ yín ti ṣe àpéjọpọ̀ àti àwọn ọjọ́ tí ẹ óò ṣe é. Yóò dára kí ẹ fàlà sábẹ́ ìlú tí ìjọ yín yóò ti ṣe àpéjọpọ̀ àti àwọn ọjọ́ tí ẹ óò ṣe é, kí ẹ sì lẹ apá yẹn nínú àkìbọnú mọ́ ara pátákó ìsọfúnni.
Akọ̀wé ìjọ ni kó bójú tó àwọn àkójọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá ní í ṣe pẹ̀lú àpéjọpọ̀ àti àwọn ìfilọ̀ ní àwọn ìpàdé ọjọ́ iwájú. Ó dára kí gbogbo alàgbà fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ní kíkún láti rí i dájú pé a bójú tó àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú àpéjọpọ̀ náà ní kánmọ́kánmọ́, pẹ̀lú ìtara ọkàn, àti lọ́nà tó gbéṣẹ́.]
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]
Àwọn Àkókò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ
Friday: 9:20 òwúrọ̀ - 4:50 ìrọ̀lẹ́
Saturday: 9:00 òwúrọ̀ - 4:30 ìrọ̀lẹ́
Sunday: 9:00 òwúrọ̀ - 3:20 ìrọ̀lẹ́