ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/98 ojú ìwé 7
  • Àpótí Ìbéèrè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àpótí Ìbéèrè
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé O Máa Ń Mú Kí Àwọn Ìpàdé Ìjọ Gbéni Ró?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Bí Àwọn Ìpàdé Ṣe Lè Fún Wa Ní Ìdùnnú Púpọ̀ Sí I
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àǹfààní Tó O Máa Rí Ní Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Pé Jọ Láti Jọ́sìn?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 4/98 ojú ìwé 7

Àpótí Ìbéèrè

◼ Kí ni a lè ṣe láti ṣèrànwọ́ láti mú kí ìgbéṣẹ́ àwọn ìpàdé wa sunwọ̀n sí i?

Àwọn kan lè ní ìtẹ̀sí láti ronú pé àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nìkan ló ni ẹrù iṣẹ́ mímú kí àwọn ìpàdé ìjọ yọrí sí rere nítorí pé àwọn ló ń darí wọn, tí wọ́n sì ń bójú tó apá tí ó pọ̀ jù lọ. Ní ti gidi, gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan lè fi kún àwọn ìpàdé tí ó gbádùn mọ́ni tí ó sì ṣàǹfààní. A lè ṣèrànwọ́ láti mú kí àwọn ìpàdé túbọ̀ gbéṣẹ́ ní àwọn ọ̀nà mẹ́wàá tí ó tẹ̀ lé e yìí:

Múra sílẹ̀ ṣáájú. Nígbà tí a bá múra sílẹ̀ dáadáa, àwọn ìpàdé máa ń gba ọkàn-ìfẹ́ wa. Nígbà tí gbogbo wa bá ṣe èyí, àwọn ìpàdé máa ń túbọ̀ tani jí, wọ́n sì ń gbéni ró. Pésẹ̀ déédéé. Pípésẹ̀ tí ọ̀pọ̀ bá pésẹ̀ túbọ̀ ń fún gbogbo ẹni tí ó pésẹ̀ níṣìírí, ó ń fún ìmọrírì fún ìjẹ́pàtàkì pípésẹ̀ lókun. Dé lákòókò. Bí a bá wà lórí ìjókòó kí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó bẹ̀rẹ̀, a lè dara pọ̀ nínú orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀, a sì lè tipa báyìí jàǹfààní ní kíkún láti inú ìpàdé. Gbára dì dáadáa wá. Nípa mímú Bíbélì wa àti ìtẹ̀jáde tàbí àwọn ìtẹ̀jáde tí a ń lò nígbà ìpàdé wá, a lè máa fọkàn bá a lọ kí a sì túbọ̀ lóye ohun tí a jíròrò dáadáa sí i. Yẹra fún ìpínyà ọkàn. A lè fetí sílẹ̀ dáadáa sí i nígbà tí a bá jókòó sí apá iwájú. Sísọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́ àti rírìn lọ sí ilé ìtura lóòrèkóòrè lè mú kí àwa àti àwọn ẹlòmíràn pàdánù ìpọkànpọ̀. Jẹ́ olùkópa. Nígbà tí púpọ̀ sí i lára wa bá ń nawọ́, tí a sì ń dáhùn, àsọjáde ìgbàgbọ́ wa ń fún ọ̀pọ̀ sí i níṣìírí, ó sì ń gbé wọn ró. Sọ àwọn ìdáhùn ṣókí. Èyí ń fún ọ̀pọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó ní àǹfààní láti ṣàjọpín. Kí a fi ìdáhùn ṣókí wa mọ sórí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a ń kẹ́kọ̀ọ́. Ṣe àwọn iṣẹ́ àyànfúnni. Gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run tàbí gẹ́gẹ́ bí olùkópa nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, múra sílẹ̀ dáadáa, ṣe ìfidánrawò ṣáájú, sì gbìyànjú láti má ṣe yẹ iṣẹ́ àyànfúnni rẹ sílẹ̀. Gbóríyìn fún àwọn olùkópa. Sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa bí o ṣe mọrírì ìsapá wọn tó. Èyí ń gbé wọn ró, ó sì ń sún wọn láti túbọ̀ ṣe dáadáa sí i ní ọjọ́ iwájú pàápàá. Ẹ máa fún ara yín níṣìírí lẹ́nì kìíní-kejì. Ìkíni onínúure àti ìjíròrò tí ń gbéni ró, ṣáájú àti lẹ́yìn àwọn ìpàdé ń fi kún ìgbádùn àti àǹfààní tí a ń jèrè láti inú lílọ sí àwọn ìpàdé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́