Báa Ṣe Lè Lánìímọ́ Ìbánifèròwérò
1 Ọ̀kan lára ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà “fèrò wérò,” ni “láti bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ débi táa ó fi yí ìwà tàbí èrò rẹ̀ padà.” Bí o bá fẹ́ túbọ̀ jáfáfá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, o gbọ́dọ̀ mọ bí o ṣe lè fèrò wérò pẹ̀lú àwọn tí o ń bá pàdé. (Ìṣe 17:2-4) Ṣùgbọ́n báwo lo ṣe lè ṣe é?
2 Ibi Ríronú Jinlẹ̀ Ló Ti Ń Bẹ̀rẹ̀: Nígbà tí o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì, ríronú nípa ohun tí o ń kọ́ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. Bí àwọn kókó kan nínú ohun tí o ń kọ́ kò bá yé ọ, wá àyè láti ṣe ìwádìí díẹ̀, kí o sì ronú jinlẹ̀ lórí ìdáhùn tí o bá rí. Má fi mọ sórí lílóye àlàyé tí a ṣe nìkan, ṣe ni kí o tún gbìyànjú láti lóye ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àlàyé náà.
3 Mímúrasílẹ̀ fún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wà Lára Ẹ̀: Ronú nípa bí wàá ṣe ṣàlàyé òtítọ́ fún onírúurú èèyàn. Béèrè ìbéèrè kan tí ń múni ronú jinlẹ̀ láti fi ru ìfẹ́ sókè. Pinnu bí o ṣe lè mú kókó kan nínú Ìwé Mímọ́ wọnú ọ̀rọ̀ rẹ, kí o sì báni fèrò wérò nípa rẹ̀. Ronú ṣáájú nípa àtakò tí àwọn èèyàn lè ṣe, kí o sì ronú nípa bí o ṣe lè jíròrò wọn. Ṣàwárí kókó pàtàkì tó wà nínú ìtẹ̀jáde tí o fẹ́ fi lọni, tí o mọ̀ pé ó máa bá ẹni tí o fẹ́ fi í lọ mu dáadáa.
4 Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù: Jésù fi àpẹẹrẹ tó dára jù lọ lélẹ̀ ní ti bí a ṣe lè fèrò wérò láti inú Ìwé Mímọ́. Láti ṣàyẹ̀wò kínníkínní lórí bí òún ṣe kọ́ni, yẹ àkọsílẹ̀ tó wà ní Lúùkù 10:25-37 wò. Kíyè sí ìgbésẹ̀ yìí: (1) Nígbà tí o bá ń dáhùn ìbéèrè àwọn èèyàn, darí wọn sínú Ìwé Mímọ́. (2) Sọ pé kí wọ́n sọ èrò ọkàn wọn, kí o sì yìn wọ́n nígbà tí wọ́n bá fi ìfòyemọ̀ dáhùn. (3) Rí i dájú pé o ṣàlàyé bí ìbéèrè náà ṣe ní í ṣe pẹ̀lú Ìwé Mímọ́. (4) Lo àpèjúwe kan tí ń wọni lọ́kàn láti rí i dájú pé ẹni náà lóye ohun tí ìdáhùn náà túmọ̀ sí gan-an.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, October 15, 1986, ojú ìwé 23 àti 24, ìpínrọ̀ 8 sí 10.
5 Lo Àwọn Irin Iṣẹ́ Tí Wọ́n fún Wa: A tẹ ìwé pẹlẹbẹ Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó jáde kí a lè máa mú un dání fún lílò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àwọn ìdáhùn sí àwọn tó lè fẹ́ dènà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, àti àwọn kókó tí a lè fi báni fèrò wérò ń mú kí a mọ bí a ṣe lè bá àwọn èèyàn fèrò wérò. Ìwé kékeré yìí jẹ́ irin iṣẹ́ tó yẹ ká máa mú dání nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ ìsìn, kí a má sì máa lọ́ tìkọ̀ láti lò ó nígbà tí a bá ń báwọn èèyàn jíròrò láti inú Bíbélì.
6 Lílánìímọ́ ìbánifèròwérò yóò mú kí òye rẹ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni pọ̀ sí i. Èyí yóò mú àwọn ìbùkún jìngbìnnì wá bá ọ àti àwọn tí o bá bá sọ̀rọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.