Ṣé Ò Ń Lo Ìwé Náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó?
1. Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Jésù ṣe kọ́ àwọn èèyàn?
1 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń gbìyànjú láti bá àwọn èèyàn “fèrò-wérò látinú Ìwé Mímọ́.” (Ìṣe 17:2, 3; 18:19) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, ẹni tó sábà máa ń fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́, tó sì máa ń lo àkàwé láti jẹ́ káwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ lóye ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run. (Mát. 12:1-12) A ṣe ìwé náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó kó lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fèrò wérò látinú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn.
2. Báwo la ṣe lè lo ìwé náà Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó láti múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó gbéṣẹ́?
2 Bá A Ṣe Lè Múra Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó Gbéṣẹ́: Lójú ìwé 2 sí 7, nínú ìwé náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó a lè rí àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó lè mú kí ẹni tá à ń bá sọ̀rọ̀ fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Kíkọ́ béèyàn ṣe lè lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ lóríṣiríṣi àti lílò wọ́n, ní pàtàkì láwọn ìpínlẹ̀ tá a ti ń wàásù déédéé, kò ní jẹ́ ká máa sọ ohun kan náà ṣáá nígbà gbogbo, kàkà bẹ́ẹ̀, á jẹ́ kí ìwàásù wa túbọ̀ gbéṣẹ́, ká sì tún mọ bá a ti ń bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. A lè ka ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ jáde tààràtà látinú ìwé náà nígbà tá a bá ń jẹ́rìí lórí tẹlifóònù tàbí nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ látorí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tí wọ́n gbé sẹ́nu ọ̀nà nínú àwọn ilé onígéètì tí kò rọrùn láti wọ̀.
3. (a) Kí ló wà lójú ìwé 7 sí 13 nínú ìwé kékeré náà tó lè ràn wá lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? (b) Àwọn wo ni ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 13 sí 16 lè wúlò fún?
3 Bá A Ṣe Lè Borí Àwọn Ọ̀rọ̀ Tó Lè Bẹ́gi Dínà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀: Kó o tó lọ wàásù, o lè ronú lórí ohun táwọn èèyàn lè sọ ní ìpínlẹ̀ yín láti bẹ́gi dí ìjíròrò rẹ, kó o sì lo àkókò díẹ̀ láti ṣàyẹ̀wò ojú ìwé 7 sí 13 láti mọ ohun tó o lè sọ. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kó o bá àwọn ẹlẹ́sìn Búdà, Híńdù, Júù tàbí Mùsùlùmí pàdé lóde ẹ̀rí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìsọfúnni tó wà lójú ìwé 13 sí 16 lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.
4. Báwo la ṣe lè lo Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò tó wà lẹ́yìn Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun nígbà tí wọ́n bá gbé ìbéèrè dìde tàbí tí wọ́n bá dá ọ̀rọ̀ kan tó ta kókó sílẹ̀?
4 Bá A Ṣe Lè Dáhùn Ìbéèrè: Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò tó wà lójú ìwé 1840 sí 1853 lẹ́yìn Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun tún lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n bá gbé ìbéèrè dìde tàbí tí wọ́n bá dá ọ̀rọ̀ kan tó ta kókó sílẹ̀. O kàn lè sọ fún ẹni náà pé, o fẹ́ fi ohun pàtàkì kan hàn án lórí ọ̀rọ̀ náà, kó o wá ṣí ẹ̀yìn Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe la to àwọn àkòrí náà tẹ̀ léra wọn lọ́nà a b d, lọ sí àkòrí tó o rò pé ó bá ohun tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò mu. Kó o wá fojú wá ìsọ̀rí tá a fi àwọ̀ dúdú kirikiri kọ. Tó o bá ti rí ọ̀rọ̀ tó bá ohun tẹ́ ẹ̀ ń jíròrò mu, kà á jáde ní tààràtà. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé bí Ìwé Mímọ́ ṣe péye tó lẹ̀ ń sọ̀rọ̀ lé lórí, o lè rí ọ̀rọ̀ tó bá a mu lábẹ́ àkòrí náà “Bíbélì.”
5. Báwo la tún ṣe lè lo Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò tó wà lẹ́yìn Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun?
5 Ọ̀nà Tá A Tún Lè Gbà Lò Ó: Àwọn kan máa ń fi Bíbélì àti ẹ̀dà kan ìwé kékeré yìí síbi iṣẹ́ tàbí sí ilé ìwé kí wọ́n lè rí i lò láti dáhùn irú àwọn ìbéèrè bíi, ‘Kí nìdí tẹ́ ò kì í fi í ṣọdún?’ ‘Kí nìdí tẹ́ ò fi gbà gbọ́ nínú iná ọ̀run àpáàdì?’ Àwọn ọ̀dọ́ ti rí i pé àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ àkòrí náà, “Ìṣẹ̀dá” wúlò gan-an, àwọn ìsọfúnni tó sì wà lábẹ́ àkòrí náà “Àmúlùmálà Ìgbàgbọ́” lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti gbèjà ìgbàgbọ́ wọn tí wọ́n bá ń fúngun mọ́ wọn láti dara pọ̀ nínú àdúrà òwúrọ̀ níléèwé. Ṣó o fẹ́ lọ kí ẹnì kan tí èèyàn rẹ̀ kú? Àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ àkòrí náà, “Ikú” àti “Àjíǹde” lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù wọ́n nínú. Ìwé yìí tún láwọn ìsọfúnni tó wúlò fún àwọn tó fẹ́ sọ àsọyé àtàwọn tó fẹ́ darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá.
6. Kí nìdí tá a fi ń wàásù?
6 Ìdí tá a fi ń wàásù kì í ṣe láti fi hàn pé a lè borí àríyànjiyàn, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe láti wulẹ̀ fún àwọn èèyàn ní ìsọfúnni. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la fẹ́ báwọn èèyàn fèrò wérò látinú Ìwé Mímọ́. Bá a ṣe ń lo Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò tó wà lẹ́yìn Ìwé Mímọ́ ní Ìtúmọ̀ Ayé Tuntun àti ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó lọ́nà tó dáa, ńṣe là ń fi hàn pé à ń fiyè sí ẹ̀kọ́ wa nígbà gbogbo.—1 Tím. 4:16.