Àpótí Ìbéèrè
◼ Ǹjẹ́ ó yẹ ká pàtẹ́wọ́ nígbà tí a bá kéde pé a gba ẹni tí a yọ lẹ́gbẹ́ padà?
Nítorí inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run, ó ti pèsè ọ̀nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu tí àwọn oníwà àìtọ́ tó ronú pìwà dà fi lè tún rí ojú rere rẹ̀, kí a sì gbà wọ́n padà sínú ìjọ Kristẹni. (Sm. 51:12, 17) Bí èyí bá ṣẹlẹ̀, a rọ̀ wá pé kí a jẹ́ kí ó dá àwọn tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn bẹ́ẹ̀ lójú pé a nífẹ̀ẹ́ wọn.—2 Kọ́r. 2:6-8.
Àmọ́ ṣá o, bí inú wa ti máa ń dùn gidigidi nígbà tí a bá gba ẹbí tàbí ojúlùmọ̀ wa kan padà, ó yẹ kí ìparọ́rọ́ tí ń fi iyì hàn wáyé nígbà tí a bá kéde pé a gba ẹnì kan padà nínú ìjọ. Ilé Ìṣọ́, October 1, 1998, ojú ìwé 17, ṣàlàyé nípa ọ̀ràn yìí pé: “Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ rántí pé, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn mẹ́ńbà ìjọ ni kò mọ ipò nǹkan náà tí ó mú kí a yọ ẹnì kan lẹ́gbẹ́ tàbí tó mú kí a gbà á padà. Ní àfikún sí i, àwọn kan lè wà tí ìwà àìtọ́ tí ẹni tí ó ronú pìwà dà náà hù ti bà lọ́kàn jẹ́ tàbí bí nínú gidigidi—bóyá fún ìgbà pípẹ́ pàápàá. Nítorí náà, bí a ti ń gba ìmọ̀lára àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ rò lórí ọ̀ràn yìí, yóò dára kí a pa ayọ̀ wa mọ́ra nígbà tí a bá kéde ìgbàpadà onítọ̀hún, a lè jẹ́ kí ó di ìgbà tó bá ku àwa pẹ̀lú rẹ̀ nìkan.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a láyọ̀ gidigidi láti rí i pé ẹnì kan padà sínú òtítọ́, kò ní dáa pé ká pàtẹ́wọ́ nígbà tí a bá gbà á padà.