ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/00 ojú ìwé 1
  • Ìhìn Rere Là Ń Wàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìhìn Rere Là Ń Wàásù
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Àwọn Tí Ń mú Ìhìn Rere Ohun Tí Ó Dára Jù Wá’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ẹ Máa Fara Wé Jèhófà Ọlọ́run Wa, “Ọlọ́run Aláyọ̀”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • “Ìhìn Rere”!
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Ìhìn Rere Tó Yẹ Kí Gbogbo Èèyàn Gbọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
km 3/00 ojú ìwé 1

Ìhìn Rere Là Ń Wàásù

1 Ẹ wo àǹfààní àgbàyanu táa ní láti máa sọ “ìhìn rere àwọn ohun rere!” (Róòmù 10:15) Ọ̀rọ̀ tó máa ń tuni lára la fẹ́ sọ fún àwọn èèyàn tí pákáǹleke àti àìnírètí yí ká. Báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ pé “ìhìn rere ohun tí ó dára jù” la ń sọ?—Aísá. 52:7.

2 Ọ̀rọ̀ Nípa Ohun Rere Ni Kóo Múra Láti Sọ: Ìjíròrò wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa mú àwọn èèyàn lọ́kàn yọ̀ bó bá jẹ́ pé àwọn ohun tó ń gbéni ró là ń sọ. Nítorí náà, nígbà tí a bá ń múra ọ̀rọ̀ tí a fẹ́ bá àwọn èèyàn sọ, tí a sì ń ṣàyẹ̀wò ìtẹ̀jáde tí a fẹ́ fi lọ̀ wọ́n, ó yẹ ká tẹnu mọ́ àwọn ohun rere inú ọ̀rọ̀ wa. Nípa fífi ìtara sọ fáwọn èèyàn nípa ìrètí tí Bíbélì fún wa, tí a sì ń fi hàn pé ó dá wa lójú, a lè máa retí àbájáde tí ń mórí yá.—Òwe 25:11.

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ ká bá àwọn èèyàn kẹ́dùn nígbà tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ nípa bí ipò ayé tí ń burú sí i ṣe ń bá wọn fínra, síbẹ̀, ó yẹ ká sọ fún wọn pé Ìjọba Ọlọ́run ló lè yanjú ìṣòro aráyé ní ti tòótọ́. Kódà nígbà tí a bá ń jíròrò nípa “ọjọ́ ẹ̀sàn” Jèhófà tí ń bọ̀, a ní láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ bí èyí, ní ti gidi, ṣe jẹ́ “ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù.” (Aísá. 61:1, 2) A lè mú un dá àwọn olùgbọ́ wa lójú pé gbogbo ohun tí Jèhófà bá ṣe yóò mú ayọ̀ ńláǹlà wá nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àbájáde rẹ̀ á sì dáa lọ́pọ̀lọpọ̀.

4 Sọ Òtítọ́ Náà Tìdùnnútìdùnnú: Bí àwọn èèyàn bá rí i pé ayọ̀ kún ojú wa, tí ohùn wa sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ wa dá wa lójú, wọ́n túbọ̀ máa ń fẹ́ láti tẹ́tí sílẹ̀. Bí a bá ń fi hàn pé a lẹ́mìí pé nǹkan á ṣẹnuure, àwọn olùgbọ́ wa á fòye mọ̀ pé à ń “yọ̀ nínú ìrètí.” (Róòmù 12:12) Nípa báyìí, wọ́n lè túbọ̀ fẹ́ láti kọbi ara sí ìhìn rere náà. Dájúdájú, gbogbo ìgbà la ní ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tó fi yẹ ká fi ẹ̀mí pé nǹkan á ṣẹnnure hàn nínú gbogbo apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ká sì máa yọ̀.

5 Gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìhìn rere, iṣẹ́ wa ju sísọ̀rọ̀ fáwọn èèyàn lọ. Iṣẹ́ ìwàásù tí a ń ṣe ń mú kí àwọn èèyàn ní ìrètí tó dájú pé ìgbésí ayé wọn á sunwọ̀n nísinsìnyí àti lọ́jọ́ ọ̀la. (1 Tím. 4:8) Bí a ṣe ń tọ àwọn èèyàn lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, ohun táa bá sọ yóò fi èrò inú rere táa ní hàn, yóò sì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti fetí sí ìhìn rere. Bí a ti ń fiyè sí ohun ti a ń sọ àti bí a ṣe ń sọ ọ́, ẹ jẹ́ kí a máa ru àwọn aláìlábòsí ọkàn sókè láti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere amọ́kànyọ̀ tí a ń wàásù rẹ̀!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́