Ẹ Máa Fara Wé Jèhófà Ọlọ́run Wa, “Ọlọ́run Aláyọ̀”
1 Kò sí àní-àní pé Jèhófà fẹ́ kí inú àwọn èèyàn rẹ̀ máa dùn. Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ti mú ká máa wọ̀nà fáwọn àgbàyanu ìbùkún tó máa fún ìran èèyàn lọ́jọ́ iwájú. (Aís. 65:21-25) Ó yẹ kó ṣe kedere sáwọn èèyàn pé inú wa ń dùn bá a ṣe ń wàásù “ìhìn rere ológo ti Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tím. 1:11) Ọ̀nà tá a gbà ń sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run gbọ́dọ̀ mú káwọn èèyàn rí bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ tó, àti bí ọ̀rọ̀ àwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀ ṣe jẹ wá lógún tó.—Róòmù 1:14-16.
2 Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó lè má rọrùn láti túra ká. Láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù kan, àwọn tó máa fẹ́ gbọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run lè máà tó nǹkan. Àwọn ìgbà kan tiẹ̀ lè wà tí ìṣòro ìgbésí ayé á máa bá wa fínra. Bá ò bá ní jẹ́ kí ohunkóhun ba ayọ̀ wa jẹ́, ṣe ló yẹ ká máa ronú lórí bó ṣe ṣe pàtàkì tó fáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù láti wa gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń wàásù kí wọ́n sì lóye rẹ̀. (Róòmù 10:13, 14, 17) Bá a bá ń ṣàṣàrò lórí èyí, á jẹ́ ká lè máa fi tayọ̀tayọ̀ mú káwọn èèyàn mọ̀ nípa ìṣètò tí àánú sún Jèhófà ṣe ká bàa lè ní ìgbàlà.
3 Kí Ọ̀rọ̀ Wa Dá Lórí Ohun Rere: A tún ní láti máa fiyè sí ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè lo àwọn ìṣòro kan tàbí ìròyìn tó gbòde kan láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, kò yẹ kó jẹ́ àwọn nǹkan ìbànújẹ́ nìkan la ó máa ránnu mọ́. Iṣẹ́ wa ni láti wàásù “ìhìn rere ohun tí ó dára jù.” (Aísá. 52:7; Róòmù 10:15) Ọjọ́ iwájú tó dára tí Ọlọ́run ṣèlérí láti mú wá ni ìhìn rere yìí dá lé lórí. (2 Pét. 3:13) Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, lo Ìwé Mímọ́ láti “di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn.” (Aís. 61:1, 2) Èyí á ran kálukú wa lọ́wọ́ láti máa túra ká, ká sì máa sọ ohun rere fáwọn èèyàn.
4 Àwọn èèyàn ò ní ṣàìmọ̀ pé inú wa ń dùn bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ ìwàásù náà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rí i pé à ń fara wé Jèhófà, ‘Ọlọ́run wa aláyọ̀’ bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba rẹ̀ fáwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa.