Ǹjẹ́ O Ń Fìmọrírì Hàn fún Ìfẹ́ Kristi?
1 Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà ìgbésí ayé tí Ọ̀gá rẹ̀ tọ̀, ó wí pé: “Bí Jésù ti nífẹ̀ẹ́ àwọn tirẹ̀ tí wọ́n wà ní ayé, ó nífẹ̀ẹ́ wọn dé òpin.” (Jòh. 13:1) Lákòókò Ìṣe Ìrántí yìí, èrò wa dá lórí ìfẹ́ gíga jù lọ tí Kristi fi hàn. A lè fìmọrírì hàn fún ìfẹ́ yẹn nípa fífi ìgbàgbọ́ hàn nínú ìràpadà náà, nípa fífi ìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe, nípa fífara dà á “dé òpin.”—Mát. 24:13; 28:19, 20; Jòh. 3:16.
2 Fífìmọrírì Hàn fún Ìfẹ́ Kristi: Ọwọ́ Jésù dí gan-an lọ́sẹ̀ tó kẹ́yìn ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 21:23; 23:1; 24:3) Gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń fara wé Kristi, a ń sún àwa pẹ̀lú láti máa “tiraka tokuntokun” nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Lúùkù 13:24) Ǹjẹ́ o lè lo àǹfààní ètò tí a ṣe fún àfikún iṣẹ́ ìjẹ́rìí lóṣù April nípa fífi kún àkókò tí wàá lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́?
3 Lọ́dún yìí, ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Wednesday, April 19 ni ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa bọ́ sí. Èèyàn mélòó ló máa wá síbi ayẹyẹ pàtàkì yìí? Ní pàtàkì, ọwọ́ wa lọ̀rọ̀ ọ̀hún kù sí o. Ṣé o ti kọ orúkọ àwọn tóo fẹ́ pè—àwọn tí o ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn mìíràn tó ń fìfẹ́ hàn, àwọn ìbátan rẹ, àwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àti àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ? Ṣé o ti bá wọn sọ̀rọ̀, ṣé o sì ti sọ fún wọn pé inú ẹ á dùn tí wọ́n bá wá? Ṣé wàá rán wọn létí bí Ìṣe Ìrántí bá ku ọjọ́ mélòó kan? Ǹjẹ́ wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ láti lè débẹ̀? Àwọn alàgbà pẹ̀lú ní láti ké sí àwọn tí kì í lọ wàásù mọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé alẹ́ ọjọ́ kan láàárín ọ̀sẹ̀ ni a máa ṣe Ìṣe Ìrántí, tí kì í ṣe lópin ọ̀sẹ̀, síbẹ̀ ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa pésẹ̀.
4 Múra Wá O: Ó ṣe pàtàkì pé ká múra sílẹ̀, ká sì ní èrò inú tó yẹ nígbà táa bá wá síbi Ìṣe Ìrántí. Pọ́ọ̀lù gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n fi bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ṣe pàtàkì tó sọ́kàn. (1 Kọ́r. 11:20-26) Ẹ lè ka orí ìkẹtàlá sí ìkẹtàdínlógún nínú Ìhìn Rere Jòhánù lákòókò tí ẹ bá ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé yín, kí ẹ sì wá jẹ́ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé ṣàlàyé ohun tí ìrúbọ Jésù túmọ̀ sí fún un. Ẹ má ṣe gbàgbé láti ka Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ fún ọ̀sẹ̀ Ìṣe Ìrántí pẹ̀lú!
5 Ìfẹ́ táa ní sí Kristi jinlẹ̀ gidigidi, ìfẹ́ yìí yóò sì máa bá a nìṣó, kódà, lẹ́yìn April 19. A múra tán láti máa fi ìfẹ́ táa ní sí i hàn títí láé! Ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tọdún yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ fún ìpinnu yẹn lágbára.