Àpótí Ìbéèrè
◼ Ta lo yẹ kó gbàdúrà ní ìpàdé ìjọ?
Àdúrà nínú ìjọ jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn wa. Ṣíṣojú fún àwọn ẹlòmíràn níwájú Jèhófà jẹ́ àǹfààní iyebíye, ó sì jẹ́ ẹrù iṣẹ́ ńláǹlà. Nítorí bó ti ṣe pàtàkì tó yìí, ó yẹ kí àwọn alàgbà lo òye nígbà tí wọ́n bá ń pinnu àwọn arákùnrin tó tóótun láti gbàdúrà ní ìpàdé. Àwọn arákùnrin tó ti ṣe batisí, tí yóò ṣojú fún ìjọ gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn Kristẹni òjíṣẹ́ tó dàgbà dénú, tí a mọ̀ pé wọ́n jẹ́ àpẹẹrẹ rere, tí ìjọ sì bọ̀wọ̀ fún. Àdúrà tí wọ́n gbà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ àti tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ gbọ́dọ̀ fi ipò ìbátan rere pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run hàn. Àpilẹ̀kọ inú Ilé Ìṣọ́, May 15, 1986, tí ó ní àkọlé náà “Fífi Ọkàn Ìrẹ̀lẹ̀ Gbàdúrà Níwájú Àwọn Ẹlòmíràn,” (Gẹ̀ẹ́sì), mẹ́nu kan àwọn ìlànà pàtàkì tó ń ṣèrànwọ́ ní ti gidi fún àwọn tí ń ṣojú fún ìjọ nínú àdúrà.
Àwọn alàgbà kò ní jẹ́ kí arákùnrin kan gbàdúrà tí a bá mọ̀ pé ìwà rẹ̀ ń kọni lóminú tàbí tí kò fi bẹ́ẹ̀ bìkítà. A kò ní yan arákùnrin tó bá jẹ́ aláìní-tẹ̀ẹ́lọ́rùn tàbí tó máa ń fẹ́ lo àdúrà níwájú ọ̀pọ̀ ènìyàn láti sọ èdè àìyedè tó ní pẹ̀lú ẹlòmíì jáde. (1 Tím. 2:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́langba ti lè ṣe batisí, àwọn alàgbà ní láti pinnu bóyá ó dàgbà dénú tó nípa tẹ̀mí láti gbàdúrà lórúkọ ìjọ.—Ìṣe 16:1, 2.
Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, níbi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá, ó lè pọn dandan pé kí arábìnrin kan tó ti ṣe batisí gbàdúrà bí kò bá sí arákùnrin tó tóótun níbẹ̀ láti ṣojú fún àwùjọ náà. Arábìnrin náà gbọ́dọ̀ fi ìbòrí tó yẹ bo orí rẹ̀. Bó bá lọ ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin tó tóótun kò ní sí níbi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá kan, kí àwọn alàgbà yan arábìnrin tó tóótun láti mú ipò iwájú.
Ó jẹ́ àṣà pé kí alága Ìpàdé Àsọyé fún Gbogbo Ènìyàn gbàdúrà ìbẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní àwọn ìpàdé ìjọ yòókù, níbi tí àwọn arákùnrin tó tóótun bá ti pọ̀, a lè ké sí ẹlòmíràn yàtọ̀ sí arákùnrin tí yóò bẹ̀rẹ̀ ìpàdé náà tàbí yàtọ̀ sí arákùnrin tí a yàn láti ṣe apá tó kẹ́yìn, láti gba àdúrà ìbẹ̀rẹ̀ tàbí àdúrà ìparí. Bó ti wù kó rí, a gbọ́dọ̀ sọ fún arákùnrin tí a óò pè láti gbàdúrà ní ìpàdé ìjọ ṣáájú, kí ó lè ronú nípa ohun tó máa sọ. Nígbà náà, yóò lè fi ìtara-ọkàn gba àdúrà tó bọ́gbọ́n mu tó sì ṣe wẹ́kú fún ìpàdé náà.
Kò pọn dandan kí irú àdúrà bẹ́ẹ̀ gùn. Nígbà tí arákùnrin kan bá ń ṣojú fún ọ̀pọ̀ ènìyàn nínú àdúrà, wọ́n sábà máa ń lóye ohun tó bá sọ, bí ó bá dìde dúró, tí ó gbóhùn sókè tó, tí ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ já gaara. Èyí á jẹ́ kí gbogbo àwọn tó pé jọ lè gbọ́ àdúrà náà, ìyẹn á sì jẹ́ kí wọ́n lè sọ látọkànwá ní ìparí àdúrà náà pé, “Àmín!”—1 Kíró. 16:36; 1 Kọ́r. 14:16.