Apá Keje: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
Ta Ló Yẹ Kó Gbàdúrà Níbi Ìkẹ́kọ̀ọ́?
1. (a) Kí nìdí tó fi dára kéèyàn fàdúrà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kó sì tún fàdúrà parí ẹ̀? (b) Ìgbà wo ló yẹ ká bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
1 Kí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bàa lè máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó ṣe pàtàkì ká máa tọrọ ìbùkún Jèhófà sórí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. (1 Kọ́r. 3:6) Nítorí náà, ó bójú mu bá a bá ti ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ kan ká máa fàdúrà bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ká sì tún máa fàdúrà parí rẹ̀. Láwọn ìgbà míì, a lè máa gbàdúrà nígbà àkọ́kọ́ ta á bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́, àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ míì wà tó jẹ́ pé àwa gan-an la ó fi òye gbé e ká tó lè mọ ìgbà tá á dáa ká bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà níbẹ̀. Kó o bàa lè ran akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́wọ́ láti lòye ìdí tí gbígbàdúrà fi ṣe pàtàkì, o lè bá a jíròrò Sáàmù 25:4, 5 àti 1 Jòhánù 5:14. O sì tún lè lo Jòhánù 15:16 láti ṣàlàyé fún un bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa gbàdúrà sí Jèhófà nípasẹ̀ Jésù Kristi.
2. Bí ọkùnrin tó jẹ́ akéde tó ti ṣèrìbọmi tàbí akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi bá bá arábìnrin kan lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́, ta ló yẹ kó gbàdúrà?
2 Ta ló yẹ kó máa gbàdúrà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Bí arákùnrin tó ti ṣèrìbọmi bá bá arábìnrin kan lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́, arákùnrin náà ló máa gbàdúrà. Lẹ́yìn ìyẹn, arábìnrin náà lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́, ṣùgbọ́n ó gbọ́dọ̀ fi nǹkan borí. (1 Kọ́r. 11:5, 10) Ẹ̀wẹ̀, bí ọkùnrin tó jẹ́ akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi àti arábìnrin kan bá jọ lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́, arábìnrin yẹn ló máa gbàdúrà. Bí ọ̀ràn bá sì rí bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ fi nǹkan borí nígbà tó bá ń gbàdúrà àti nígbà tó bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́.
3. Kí làwọn nǹkan tó yẹ kí àdúrà wa dá lé lórí níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
3 Àwọn Nǹkan Tẹ́ Ẹ Lè Gbàdúrà Lé Lórí: Kò yẹ kí àdúrà téèyàn bá gbà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gùn jàn-ànràn jan-anran, àmọ́ ó dára kí irú àdúrà bẹ́ẹ̀ dá lórí ohun tó ṣe pàtó. Èèyàn lè tọrọ ìbùkún Ọlọ́run sórí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, kéèyàn sì dúpẹ́ fún òtítọ́ tá a rí kọ́. Á tún dára kéèyàn yin Jèhófà nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìtọ́ni ti ń wá. (Aís. 54:13) A sì tún lè sọ àwọn ọ̀rọ̀ tá á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà tọkàntọkàn, àtèyí tó fi hàn pé a mọrírì ètò tí Jèhófà ń lò. (1 Tẹs. 1:2, 3; 2:7, 8) Bá a bá ń gbàdúrà pé kí Jèhófà bù kún ìsapá akẹ́kọ̀ọ́ náà kó bàa lè fi ohun tó ń kọ́ sílò, ìyẹn á ràn án lọ́wọ́ láti rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn jẹ́ “olùṣe ọ̀rọ̀ náà.”—Ják. 1:22.
4. Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn máa fi àdúrà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ kó sì tún máa fi àdúrà parí rẹ̀?
4 Àǹfààní tó wà nínú àdúrà pọ̀ gan-an ni. Ó máa ń jẹ́ kéèyàn rí ìbùkún Ọlọ́run gbà. (Lúùkù 11:13) Ó máa ń fi bí kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó hàn. Bí akẹ́kọ̀ọ́ ṣe ń fetí sí àdúrà wa, òun náà á máa kọ́ bóun ṣe lè máa gbàdúrà. (Lúùkù 6:40) Àti pé bó bá jẹ́ pé ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run àti ìmọrírì tá a ní fáwọn ànímọ́ rẹ̀ títayọ ló mú ká gbàdúrà sí i, ìyẹn lè ran akẹ́kọ̀ọ́ yẹn lọ́wọ́ láti sọ ara rẹ̀ di ọ̀rẹ́ Jèhófà.