Àpótí Ìbéèrè
◼ Ǹjẹ́ ó yẹ ká gbàdúrà nígbà tá a bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu ọ̀nà?
Ọ̀pọ̀ Àǹfààní ló wà nínú fífi àdúrà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká sì fi àdúrà parí rẹ̀. Tá a bá gbàdúrà, ńṣe là ń bẹ Jèhófà pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ nígbà ìjíròrò náà. (Lúùkù 11:13) Àdúrà tún ń jẹ́ kí ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mọ bí ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ń kọ́ ti ṣe pàtàkì tó, á sì tún jẹ́ kí òun náà mọ bá a ṣe ń gbàdúrà. (Lúùkù 6:40) Torí náà, kò yẹ kó pẹ́ rárá ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́ ṣá o, níwọ̀n bi ipò nǹkan kì í ti í dọ́gba, kí ẹni tó ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lo òye láti pinnu bóyá òun máa gbàdúrà nígbà tó bá fẹ́ kọ́ ẹni náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́nu ọ̀nà.
Ohun pàtàkì kan tó yẹ kẹ́ ẹ ronú nípa rẹ̀ ni ibi tẹ́ ẹ ti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Bí kò bá sí ẹni tó máa dí yín lọ́wọ́, ẹ lè dọ́gbọ́n gbàdúrà ṣókí láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ ẹni tẹ́ ẹ ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, kẹ́ ẹ sì tún fi àdúrà parí rẹ̀. Àmọ́, bí èyí bá máa pe àfiyèsí àwọn èèyàn sí yín tàbí tí kò bá akẹ́kọ̀ọ́ náà lára mu, ó máa dára kẹ́ ẹ dúró dìgbà tẹ́ ẹ máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà níbi tí kò ti ní sí ìdíwọ́. Ibi yòówù kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ti máa wáyè, a gbọ́dọ̀ lo òye láti pinnu ìgbà tá a máa bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 2005, ojú ìwé 4.