“Ẹ Máa Gbàdúrà ní Ọ̀nà Yìí”
ǸJẸ́ o mọ Àdúrà Olúwa? Àdúrà àfiṣàpẹẹrẹ tí Jésù Kristi kọ́ni là ń pè bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Jésù ń ṣe ohun tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Ìwàásù Lórí Òkè, ó sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí.” (Mátíù 6:9) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù ló fi àdúrà náà lélẹ̀, wọ́n sábà máa ń pè é ní Àdúrà Olúwa, a sì tún mọ̀ ọ́n sí Baba Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run.—Paternoster ní èdè Látìn.
Ọ̀pọ̀ èèyàn yíká ayé ló mọ Àdúrà Olúwa sórí wọ́n sì máa ń kà á lákàtúnkà, kódà ojoojúmọ́ làwọn kan ń kà á. Ọ̀pọ̀ ló ti ka àdúrà yìí sókè ketekete níléèwé àti níbi àwọn ayẹyẹ ìsìn. Kí ló mú káwọn èèyàn ka Àdúrà Olúwa sí tó bẹ́ẹ̀?
Cyprian tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní ọ̀rúndún kẹta kọ̀wé pé: “Àdúrà wo ló tún lè múni sún mọ́ Ọlọ́run ju èyí tí Jésù kọ́ni lọ . . . ? Àdúrà wo sí Baba ló tún lè jóòótọ́ ju èyí tí Ọmọ, tóun fúnra rẹ̀ jẹ́ Òtítọ́, fi lé wa lọ́wọ́?”—Jòhánù 14:6.
Ìwé Katikísìmù Ìjọ Kátólíìkì sọ pé Baba Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run jẹ́ àdúrà tó “ṣe kókó fáwọn Kristẹni.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia pàápàá gbà pé àdúrà yìí ṣe pàtàkì púpọ̀ fún gbogbo àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ó sì pè é ní ọ̀kan pàtàkì lára “àwọn gbólóhùn tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ẹ̀sìn Kristẹni.”
Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ gbójú fo kókó náà dá pé, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka Àdúrà Olúwa ni kò fi bẹ́ẹ̀ mọ ìtumọ̀ àdúrà náà. Ìwé ìròyìn Ottawa Citizen tó ń jáde lórílẹ̀-èdè Kánádà sọ pé: “Bó o bá jẹ́ ẹni tó máa ń lọ sí Ṣọ́ọ̀ṣì tàbí tó o ti lọ rí, ó ṣeé ṣe kó o lè ka Àdúrà Olúwa lólówuuru, àmọ́ tó bá di pé kó o fara balẹ̀ kà á kó sì yé ọ, ó lè ṣòro fún ọ.”
Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣe pàtàkì ká lóye àdúrà tí à ń gbà sí Ọlọ́run? Kí nìdí tí Jésù fi kọ́ wa ní Àdúrà Olúwa? Kí lo lè rí kọ́ nínú rẹ̀? Ó yá, jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò.