Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Mar. 15
“Ní orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé làwọn èèyàn ti mọyì ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni. [Ka ọ̀rọ̀ tó wà ní ojú ìwé 3, ìpínrọ̀ 1.] Ṣùgbọ́n kí lo ti rò ó sí, ṣé ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni, irú èyí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ tá a fẹ́ kà yìí, wúlò fún wa lóde òní? [Ka Mátíù 5:21, 22a. Lẹ́yìn náà, jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Jésù àti àǹfààní tó wà nínú wọn.”
Ile Iṣọ Apr. 1
“Ǹjẹ́ o ti gbọ́ rí táwọn kan ń sọ pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti Bíbélì ta kora? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tó fà á tí ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìsìn fi máa ń fa awuyewuye. Ṣùgbọ́n ó tún fẹ̀rí hàn pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tó jinlẹ̀ bá Bíbélì mu.” Fi ojú ìwé 6 àti 7 hàn án. Lẹ́yìn náà, ka Oníwàásù 1:7.
Jí Apr. 8
“Ọ̀pọ̀ èèyàn làwọn òkè máa ń wù nítorí bí wọ́n ṣe rẹwà, ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o mọ̀ pé wọ́n jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó so ẹ̀mí àwa èèyàn àti ẹranko ró? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí táwọn òkè fi jẹ́ kòṣeémánìí àti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wọn lónìí. Ó tún mẹ́nu kan bí Ẹlẹ́dàá ò ṣe ní jẹ́ káwọn èèyàn bà á jẹ́.” Ka Sáàmù 95:4.
“Báwo lo ṣe rò pé àwọn òbí lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa kó sí ìṣòro ìgbà ọ̀dọ́ tó sábà, máa ń nira? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Aísáyà 48:17, 18.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí fífi àwọn ìtọ́ni Bíbélì sílò ṣe lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti máa bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ tó jíire àti bí wọ́n ṣe lè máa tọ́ wọn sọ́nà kí wọ́n má bàa ṣe ohun tí kò tọ́.”