Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Mar. 15
“Ǹjẹ́ o rò pé àwọn ẹ̀kọ́ tí Jésù fi kọ́ni wúlò lóde òní? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ó dájú pé o fara mọ́ àṣẹ yìí, èyí tí Jésù pa ní ọjọ́ tó lò kẹ́yìn ṣáájú kó tó kú. [Ka Jòhánù 15:12.] Jésù tún kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ mìíràn tó ṣeyebíye lọ́jọ́ náà. Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí fi hàn bí a ṣe lè jàǹfààní nínú wọn.”
Ilé Ìṣọ́ Apr. 1
“Àwòrán ayẹyẹ tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lò ń wò níbí yìí. [Fi iwájú àti ẹ̀yìn ìwé ìròyìn náà han onílé.] Ǹjẹ́ o mọ̀ pé òun nìkan ni ayẹyẹ tí Bíbélì pa láṣẹ fún àwọn Kristẹni pe kí wọ́n máa ṣèrántí rẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Lúùkù 22:19.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tó mú kí ayẹyẹ yìí ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ àti bó ṣe kàn ọ́.”
Jí! Apr. 8
“Ǹjẹ́ o ti ṣàkíyèsí pé lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń ṣòro fún láti rí oorun tó tó sùn? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àníyàn tàbí ìdààmú ọkàn lè wà lára ohun tó ń fa èyí. [Ka Oníwàásù 5:12.] Ìwé ìròyìn yìí gbé díẹ̀ lára àwọn ohun tó máa ń fa àìróorunsùn yẹ̀ wò, ó sì fúnni láwọn àbá tó wúlò nípa bí a ṣe lè máa rí oorun sùn dáadáa.”
“Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tó ń bani nínú jẹ́ ni pé oògùn olóró ti ba ayé ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ jẹ́? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Lọ́pọ̀ ìgbà, ibi tí ìṣòro náà ti máa ń bẹ̀rẹ̀ ni nígbà táwọn ọ̀dọ́ bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ rìn. [Ka 1 Kọ́ríńtì 15:33.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó máa ń sún àwọn ọ̀dọ́ sí bíbẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró àti ohun tí àwọn òbí lè ṣe láti dáàbò bo àwọn ọmọ wọn.”