ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/07 ojú ìwé 4
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 3/07 ojú ìwé 4

Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Ile Iṣọ Mar. 15

“Àwọn èèyàn sábà máa ń sọ nípa dídé Jésù Kristi. Ṣó o rò pé ohun tó yẹ kéèyàn máa retí ni, àbí èyí tó yẹ kéèyàn máa bẹ̀rù? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Jòhánù tóun náà kọ lára àwọn ìwé inú Bíbélì sọ nínú Ìṣípayá 22:20. [Kà á.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Kristi á gbé ṣe tó bá dé.”

Ile Iṣọ Apr. 1

“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ọjọ́ kan tí a kì í ronú nípa ìlera, ìdílé àti iṣẹ́ wa. Ibo lo rò pé a ti lè rí ìdáhùn tó ṣeé gbọ́kàn lé, tó sì máa kó àníyàn kúrò lọ́kàn wa? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nínú 2 Tímótì 3:16. [Kà á.] Ìwé ìròyìn yìí sọ bí Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ní onírúurú ọ̀nà.”

Jí! Jan.-Mar.

“Ǹjẹ́ o mọ̀ pé wòlíì kan ti sọ rí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ò ní sí àìsàn mọ́? [Jẹ́ kó fèsì, kó o wá ka Aísáyà 33:24.] Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì wà nínú Bíbélì tó sọ nípa ìgbà tí ò ní sí àìsàn mọ́. Àwọn àpilẹ̀kọ tí ìwé ìròyìn yìí jíròrò á jẹ́ kó o mọ ìgbà tí ara gbogbo ayé á dá ṣáṣá tí ò sì ní sí àìsàn mọ́.”

“Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tó ta kora làwọn ìsìn fi ń kọ́ni nípa ọtí líle. Kí lo rò pé Ọlọ́run fẹ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Jésù ṣe ni sísọ omi di wáìnì, síbẹ̀ Bíbélì ṣe ìkìlọ̀ kan fún wa, inú Òwe 20:1 ni ìkìlọ̀ náà sì wà. [Kà á.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ojú ìwòye tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì látinú Bíbélì nípa ọtí líle.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà ní ojú ìwé 24 hàn án.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́