Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Mar. 1
“Ojoojúmọ́ là ń gbọ́ pé àwọn èèyàn ń jìyà, wọ́n ń ṣàìsàn, wọ́n sì ń kú. Ṣó o rò pé a máa bọ́ lọ́wọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹsẹ Bíbélì yìí ti jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. [Ka Jòhánù 3:16.] ‘Bí Ikú Jésù Ṣe Lè Gbà Ọ́’ ni àkòrí ìwé ìròyìn yìí.”
Ile Iṣọ Apr. 1
“Ṣé wàá fẹ́ rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí? [Ka Aísáyà 2:4. Lẹ́yìn náà jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí i pé Ọlọ́run máa dá sí ọ̀ràn aráyé, ó sì máa ‘mú ọ̀ràn tọ́.’ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa ja ogun Amágẹ́dọ́nì, èyí tó máa fòpin sí gbogbo ogun. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Amágẹ́dọ́nì jẹ́, ó sì jẹ́ ká mọ ìdí tó fi yẹ ká máa fojú sọ́nà fún un.”
Jí! Jan.–Mar.
“Tí mo bá béèrè pé, ‘kí nìdí táwa èèyàn fi máa ń ṣègbéyàwó, kí sì nìdí tí Ọlọ́run fi fi ọkọ ṣe orí aya?’ Kí lo máa sọ? [Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:24. Lẹ́yìn náà jẹ́ kó fèsì.] Ìdáhùn tó sojú abẹ níkòó wà nínú àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 16 nínú Jí! tó wà lọ́wọ́ mi yìí.”
“Ǹjẹ́ o mọ ohun tí Bíbélì sọ pó yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa ṣe tó bá dọ̀ràn wíwo ìwòkuwò, fífi àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì ṣèwà hù àti ṣíṣe eré orí kọ̀ǹpútà? [Jẹ́ kó fèsì, kó o wá ṣàlàyé kókó pàtàkì tó wà nínú 1 Tẹsalóníkà 5:21.] Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . tó wà nínú ìwé ìròyìn yìí sọ ohun tó yẹ káwọn ọ̀dọ́ tó bá bẹ̀rù Ọlọ́run ronú lé lórí.” Fi àwọn àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 18 sí 27 hàn án.