Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Apr. 1
“Pẹ̀lú báwọn èèyàn ṣe ń ba àwọn ohun tó ṣeyebíye tí Ọlọ́run dá sáyé jẹ́ tí wọ́n sì ń pa á run, ṣó o rò pé ayé yìí lè là á já? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ìlérí tó ń tuni nínú yìí. [Ka Sáàmù 104:5.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ilẹ̀ ayé ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.
Ile Iṣọ May 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń sọ pé ohun táwọn bá rí nìkan làwọ́n lè gbà gbọ́. Ṣé ìwọ náà gbà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Róòmù 1:20.] Ìwé ìròyìn yìí sọ mẹ́ta lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tá a lè rí lára àwọn ohun tó dá, ó tún ṣàlàyé bí mímọ àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn ṣe lè nípa lórí wa.”
Jí! Apr.– June
“Àwọn kan gbà gbọ́ pé Ọlọ́run níbi tó máa ń kọ ẹ̀ṣẹ̀ àwa èèyàn sí. Èrò àwọn kan sì ni pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni Ọlọ́run máa ń dárí rẹ̀ jini bó ti wù kó burú tó. Kí lèrò ẹ? [Jẹ́ kó fèsì. Kó o wá ka Ìṣe 3:19.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé ọ̀nà mẹ́ta tí Bíbélì sọ pé èèyàn lè gbà rí àánú Ọlọ́run.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.
“Ṣó o rò pé gbogbo ẹ̀sìn ló dáa? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìjọsìn àwọn kan. [Ka Máàkù 7:7.] Báwo lèèyàn ṣe lè mọ̀ bóyá òótọ́ ni ẹ̀sìn kan fi ń kọ́ni tàbí ‘àṣẹ àwọn ènìyàn’? Ṣé ẹ̀sìn kankan tiẹ̀ wà tó ń fòótọ́ kọ́ni?” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 25 nínú ìwé ìròyìn yìí hàn án.