Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Apr. 15
“Ó dà bíi pé ìwà òǹrorò ti wá ń wọ́pọ̀ sí i báyìí o. [Mẹ́nu ba ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ládùúgbò gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tàbí kó o lo àpẹẹrẹ kan látinú ìwé ìròyìn yìí.] Ǹjẹ́ o mọ ohun tó jẹ́ káwọn èèyàn ya òǹrorò bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìwà òǹrorò á máa pọ̀ sí i. [Ka 2 Tímótì 3:1-5.] Ìwé ìròyìn yìí dáhùn ìbéèrè yìí, ‘Ṣé ìwà òǹrorò lè tán láyé yìí?’”
Ile Iṣọ May 1
“Bí iná ni ikú ọmọ máa ń jó àwọn òbí lára, ìrora ọkàn yẹn kì í sì í lọ bọ̀rọ̀. Ibo làwọn òbí lè yíjú sí fún ìtùnú? [Jẹ́ kó fèsì, kó o wá ka Róòmù 15:5.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò àwọn ọ̀nà mélòó kan tí Ọlọ́run gbà ń tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú.”
Jí! Apr.–June
“[Ka 1 Jòhánù 5:19] Kó o wá bi onílé pé, ‘Ǹjẹ́ o rò pé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ ló fa àwọn ìṣòro tá à ń rí nínú ayé lónìí?’ [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa bá a ṣe lè dá ‘ẹni burúkú náà’ mọ̀, ó sì jẹ́ ká mọ bá ò ṣe ní í jẹ́ kó nípa lórí wa.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 24 hàn án.
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn alákòóso ni wọ́n ní ìgbéraga. Ǹjẹ́ o rò pé ìwà yìí máa jẹ́ kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wà nínú ayé? [Jẹ́ kó fèsì.] Ohun tí Bíbélì sọ nípa ìgbéraga rèé. [Ka Òwe 16:18.] Àpilẹ̀kọ yìí ṣàlàyé àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jẹ́ onírẹ̀lẹ̀.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 26 hàn án.