Ẹ̀yin Òbí—Ẹ Gbin Àṣà Tó Dára Sínú Àwọn Ọmọ Yín
1 Wọn kì í bí àwọn àṣà tó dára mọ́ ènìyàn, èèyàn kì í sì í ṣàdédé ní wọn. Síwájú sí i, gbígbin àṣà tó dára sínú àwọn ọmọ máa ń gba àkókò. “Gbìn sínú” túmọ̀ sí “láti máa fi nǹkan kọ́ni ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé” tàbí “láti jẹ́ kó máa wọnú ẹni díẹ̀díẹ̀.” Àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa kọ́ àwọn ọmọ lọ́nà tó ṣe déédéé bí wọn yóò bá “máa bá a lọ ní títọ́ [àwọn ọmọ wọn] dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfé. 6:4.
2 Bẹ̀rẹ̀ Láti Ìgbà Ọmọ Ọwọ́: Agbára tí àwọn ọmọ kéékèèké ní láti kọ́ àwọn nǹkan tuntun kí wọ́n sì máa ṣe wọ́n kàmàmà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó sábà máa ń ṣòro fún àwọn àgbà láti kọ́ èdè tuntun, àwọn ọmọ tí kò tíì tó bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ lè kọ́ èdè méjì tàbí mẹ́ta lẹ́ẹ̀kan náà. Má ṣe ronú láé pé ọmọ rẹ kéré jù láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn àṣà tó dára. Bí a bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí fún ọmọ kan ní ìtọ́ni nípa òtítọ́ Bíbélì tí a kò sì dáwọ́ dúró, nígbà tó bá máa fi dàgbà díẹ̀, ìmọ̀ tí yóò mú kí ó jẹ́ “ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà” yóò ti kún èrò inú rẹ̀.—2 Tím. 3:15.
3 Sọ Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Dàṣà: Àṣà dídára kan tó yẹ ká gbìn sínú ọmọ bó ṣe ń dàgbà ni pé kí ó máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run déédéé. Ọ̀pọ̀ òbí bẹ̀rẹ̀ èyí nípa gbígbé àwọn ọmọ wọn dání nígbà tí wọ́n bá ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé nígbà tí àwọn ọmọ náà ṣì jẹ́ ọmọ jòjòló. Bí àwọn òbí wọn ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí déédéé ń ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti mọrírì iṣẹ́ òjíṣẹ́ kí wọ́n sì ní ìtara fún un. Àwọn òbí lè fi bí àwọn ọmọ ṣe lè kópa nípa jíjẹ́rìí nínú gbogbo apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá hàn wọ́n.
4 Fíforúkọ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run tún ń ran àwọn ọmọ lọ́wọ́. Ó ń fi àṣà tó dára kọ́ wọn, ìyẹn kíkẹ́kọ̀ọ́ àti kíkàwé lọ́nà tí yóò fi yé wọn. Wọ́n ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè jíròrò nípa Bíbélì, kí wọ́n ṣe ìpadàbẹ̀wò, kí wọ́n sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ lè sún wọn láti ṣe aṣáájú ọ̀nà kí wọ́n sì nàgà fún àwọn àkànṣe àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì tàbí tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì máa ń gbádùn rírántí ìgbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ yìí, wọ́n sì kà á sí ohun kan tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú àṣà tó dára dàgbà.
5 Ńṣe ni gbogbo wa dà bí amọ̀ lọ́wọ́ Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò náà, Jèhófà. (Aísá. 64:8) Bí amọ̀ náà bá ṣe jọ̀lọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe dùn-ún mọ tó. Bó bá sì ti gbẹ tó, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe ṣòroó mọ tó. Bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti ènìyàn náà nìyẹn. Nígbà tí wọ́n bá wà lọ́mọdé, ó máa ń túbọ̀ rọrùn láti darí wọn—bí wọ́n bá sì ṣe kéré tó nígbà yẹn, bẹ́ẹ̀ náà ni àbájáde rẹ̀ ṣe máa ń dára tó. Àwọn ọdún tí wọ́n fi wà lọ́mọdé ni wọ́n fi ń kọ́ ohun tí wọn yóò dà, ìgbà yẹn ni wọ́n ń kọ́ àṣà tó dára tàbí èyí tó burú. Gẹ́gẹ́ bí òbí tó bìkítà, tètè bẹ̀rẹ̀ sí gbin àwọn àṣà tó dára sínú àwọn ọmọ rẹ, kí wọ́n fẹ́ràn iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.