Jèhófà Ń Fi Agbára Fúnni
1 Kí lèrò tí o ní nípa àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù? Bí a ṣe ń ka ìwé Ìṣe, a mọrírì bí òun ṣe jẹ́ òṣìṣẹ́ kára nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lè ṣe gbogbo ohun tó ṣe? Ó wí pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílí. 4:13) Àwa pẹ̀lú lè jàǹfààní látinú agbára tí Jèhófà ń fúnni. Lọ́nà wo? Nípa lílo àǹfààní àwọn nǹkan mẹ́fà tó pèsè fún wa láti lè fún wa lágbára àti okun nípa tẹ̀mí.
2 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: Bó ṣe jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ máa jẹun láti máa ní okun nípa ti ara, bẹ́ẹ̀ náà la ṣe gbọ́dọ̀ máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ ara wa kí a lè máa wà láàyè nípa tẹ̀mí. (Mát. 4:4) Bíbélì ń pèsè agbára tí ń mẹ́sẹ̀ wa dúró. Láti máa bá ìtara táa ní fún òtítọ́ nìṣó, ó yẹ ká máa dá kẹ́kọ̀ọ́ ká sì máa ṣàṣàrò lọ́nà gidi lójoojúmọ́ bó bá ṣeé ṣe.—Sm. 1:2, 3.
3 Àdúrà: Ó ṣe pàtàkì láti sún mọ́ Jèhófà dáadáa, pàápàá nígbà tí a bá nílò nǹkan lákànṣe. Nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, ó máa ń fi agbára tí ń fúnni lókun fún àwọn tó bá gbàdúrà láti béèrè fún un. (Lúùkù 11:13; Éfé. 3:16) Ìwé Mímọ́ fún wa níṣìírí pé ká “ní ìforítì nínú àdúrà.” (Róòmù 12:12) Ǹjẹ́ o ń ṣe bẹ́ẹ̀?
4 Ìjọ: A tún máa ń rí okun àti ìṣírí gbà ní àwọn ìpàdé ìjọ àti nínú ìbákẹ́gbẹ́ ọlọ́yàyà tí a máa ń gbádùn níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa. (Héb. 10:24, 25) Nígbà tí ohun kan bá dà wá lọ́kàn rú, wọ́n máa ń ṣèrànwọ́ láti fún wa níṣìírí, wọ́n sì máa ń ràn wá lọ́wọ́ tìfẹ́tìfẹ́.—Òwe 17:17; Oníw. 4:10.
5 Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá: Kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá déédéé ń ràn wá lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀ sórí Ìjọba náà àti àwọn ìbùkún rẹ̀. Ara wa máa ń yá gágá nígbà tí a bá ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa Jèhófà. (Ìṣe 20:35) Kì í ṣe gbogbo wa ló lè ṣí lọ láti lọ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo wa ló lè kópa nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, ṣùgbọ́n a lè kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní àwọn ọ̀nà mìíràn.—Héb. 6:10-12.
6 Àwọn Kristẹni Alábòójútó: A máa ń jàǹfààní nínú ìṣírí àti ìrànwọ́ tí àwọn alàgbà máa ń pèsè. Jèhófà ti yàn wọ́n láti máa ṣolùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tó wà lábẹ́ àbójútó wọn. (1 Pét. 5:2) Àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò máa ń gbé àwọn ìjọ tí wọ́n ń bẹ̀ wò ró, àní gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe nígbà ayé rẹ̀.—Róòmù 1:11, 12.
7 Àpẹẹrẹ Àwọn Olóòótọ́: Ó ń fúnni lókun láti ṣàyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ afúnniníṣìírí ti àwọn olóòótọ́ òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni ti ìgbà àtijọ́ àti ti òde òní. (Héb. 12:1) Nígbà tí o bá nílò okun, kí ló dé tóò ka ọ̀kan lára àwọn ìrírí tó ń fúnni níṣìírí nínú àwọn ìwé ìròyìn wa, tàbí ìròyìn tí ń gbéni ró nínú ìwé Yearbook, tàbí díẹ̀ nínú àwọn àkọsílẹ̀ tí ń mọ́kàn yọ̀ tó sọ nípa ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tòde òní nínú ìwé Proclaimers?
8 Arákùnrin kan, tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti ń lọ sí ọgọ́rùn-ún ọdún tẹ́wọ́ gba òtítọ́ nígbà tó wà lọ́mọdé. Nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, a dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, àwọn kan tó ti dara pọ̀ mọ́ ìjọ tí wọ́n sì ń ṣe dáadáa tẹ́lẹ̀ fi ètò àjọ Jèhófà sílẹ̀. Ló bá tún wá kan ti iṣẹ́ ilé dé ilé tó rí i pé ó ṣòro fún òun. Síbẹ̀, ó gbára lé Jèhófà nígbà gbogbo. Kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Lónìí wá ńkọ́ o? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara rẹ̀ kò le dáadáa mọ́, ó ṣì jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn, ó sì ń sìn nínú Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Kò kábàámọ̀ pé òun rọ̀ mọ́ ètò àjọ Jèhófà.
9 Arábìnrin kan tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ṣe ìrìbọmi nígbà tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́tàlá. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin ní ọdún tó tẹ̀ lé e, nígbà tó sì di ọdún kẹta, wọ́n fi bàbá rẹ̀ sẹ́wọ̀n nítorí pé kò dá sí tọ̀tún tòsì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Arábìnrin yìí ṣáà gbára lé Jèhófà fún okun, ó sì ń bá a nìṣó láti máa sin Ọlọ́run tòótọ́ náà. Nígbà tó yá, ó fẹ́ arákùnrin kan tó jẹ́ olùṣòtítọ́, wọ́n sì jọ ń ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Lẹ́yìn tí wọ́n ti jẹ́ tọkọtaya fún ọdún márùndínlógójì, ọkọ rẹ̀ kú lójijì. Ló bá tún gba okun lọ́dọ̀ Jèhófà, kò sì ṣíwọ́ sísin Jèhófà títí dòní olónìí bó ti ǹ wo iwájú láti máa sin Jèhófà títí láé gẹ́gẹ́ bí ara ìdílé Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé.
10 Jèhófà máa ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lọ́wọ́, ó sì máa ń fún wọn lókun. “Ó ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀; ó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun alágbára gíga.” A lè máa gba okun láti orísun agbára tí kò láàlà yìí nípa lílo àǹfààní gbogbo ìpèsè mẹ́fà tí a mẹ́nu kàn lókè yìí. Rántí pé: “Àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà. . . . Wọn yóò sáré, agara kì yóò sì dá wọn; wọn yóò rìn, àárẹ̀ kì yóò sì mú wọn.” (Aísá. 40:29-31) Pọ́ọ̀lù gbára lé Jèhófà gidigidi fún okun, bẹ́ẹ̀ náà làwa náà sì gbọ́dọ̀ ṣe.