ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/01 ojú ìwé 1
  • Ẹ Jẹ́ Kí Gbogbo Wa Máa Bọlá fún Jèhófà àti fún Ọmọ Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Jẹ́ Kí Gbogbo Wa Máa Bọlá fún Jèhófà àti fún Ọmọ Rẹ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bọla fun Jehofa—Eeṣe ati Bawo?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ẹ Máa Bọlá fún Àwọn Tí Ọlá Tọ́ Sí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • Bọla fun Oriṣi Eniyan Gbogbo
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ẹ Máa Bọlá Fáwọn Ẹlòmíràn
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 3/01 ojú ìwé 1

Ẹ Jẹ́ Kí Gbogbo Wa Máa Bọlá fún Jèhófà àti fún Ọmọ Rẹ̀

Bí Gbogbo Àwọn Tó Bá Wá sí Ìṣe Ìrántí ní April 8 Ṣe Lè Jàǹfààní Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́

1 Àwọn wo ni wọ́n máa ń bọlá fún lọ́nà àkànṣe lóde òní? Àwọn táyé bá ka ohun tí wọ́n ṣe sóhun ńlá ni. Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, kì í pẹ́ tóhun tí wọ́n ṣe fi máa ń di ìgbàgbé. Ṣùgbọ́n àwọn ohun tó ṣe gbogbo aráyé láǹfààní lóòótọ́ ńkọ́? Èyí tó tóbi jù lọ lára wọn la máa fún láfiyèsí gidigidi bí a ṣe ń ṣe ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní April 8, 2001.

2 Ta ni ọlá tó ga jù lọ tọ́ sí? Bíbélì dáhùn pé: “Jèhófà, . . . ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo.” (Ìṣí. 4:11) Bí Jèhófà ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá, òun ni Alákòóso tó jẹ́ Ọba Aláṣẹ láyé lọ́run. Títí ayé ni ọlá yóò máa tọ́ sí i!—1 Tím. 1:17.

3 Jésù Kristi, Ọmọ Ọlọ́run, ṣe àwọn ohun pàtàkì tí yóò mú ìbùkún tí kò lópin bá aráyé. Ó ṣàfarawé Bàbá rẹ̀ lọ́nà pípé. (Jòh 5:19) Bó ṣe ṣègbọràn láìkù síbì kan àti iṣẹ́ ìsìn tó fi tòótọ́tòótọ́ ṣe mú kó “yẹ láti gba agbára àti ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti okun àti ọlá àti ògo àti ìbùkún.” (Ìṣí. 5:12) Bàbá rẹ̀ bọlá fún un nípa fífi í jọba. (Sm. 2:6-8) Ní tiwa, a óò ní àǹfààní láti bọlá fún Baba àti Ọmọ bí a ti ń ṣayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní April 8, 2001.

4 Ó bani nínú jẹ́ pé, nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn, díẹ̀ làwọn tó bọlá fún Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ lọ́nà yíyẹ. Nígbà míì, kódà àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà àtijọ́, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan kò fọkàn ṣiṣẹ́ ìsìn fún Jèhófà. Ìwà àìlọ́wọ̀ pátápátá gbáà lèyí. (Mál. 1:6) Fífi ọ̀wọ̀ tó yẹ hàn ń béèrè pé kéèyàn ṣègbọràn, kí ìyẹn sì jẹ́ nítorí ìfẹ́ téèyàn ní sí Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ àti ìmọrírì téèyàn ní fún wọn nítorí nǹkan tí wọ́n ti ṣe fún wa. Fífún wọn ní irú ọlá bẹ́ẹ̀ túmọ̀ sí pé a óò máa fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ọ̀wọ̀ hàn, tí a óò máa ka Jèhófà àti Jésù sí nínú gbogbo ohun tí a bá ń ṣe. Ìjọ Kristẹni máa ń sakun láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn, ó sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

5 Àkókò Àkànṣe Kan Láti Bọlá fún Wọn: Ìgbà ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ni ìgbà tó ṣe pàtàkì jù lọ táwọn èèyàn Jèhófà máa ń péjọ lọ́dún. Gbogbo ẹni tó bá fẹ́ láti sin Jèhófà àti láti bọlá fún un ló yẹ kó wà níbẹ̀. (Lúùkù 22:19) A retí pé láfikún sí àwa mílíọ̀nù mẹ́fà ògbóṣáṣá Ẹlẹ́rìí, àwọn olùfìfẹ́hàn tó máa wá yóò jẹ́ kí iye wa kọjá mílíọ̀nù mẹ́rìnlá. Àǹfààní àtàtà mà lèyí o láti bọlá fún Baba wa ọ̀run! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ni ayẹyẹ náà yóò pe àfiyèsí sí, ọlá àti ọ̀wọ̀ tí a bá fi hàn nítorí ohun tó ṣe yóò fògo fún Baba tó rán an.—Jòh. 5:23.

6 Kí la lè ṣe láti ti ayẹyẹ àkànṣe yìí lẹ́yìn? A lè ran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn lọ́wọ́ láti jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá, níbi tó bá sì ti yẹ bẹ́ẹ̀, lo inú rere láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè débẹ̀. Ṣàlàyé ète tí àsọyé náà wà fún. Fi wọ́n han àwọn ẹlòmíràn. Ohun tí wọ́n bá rí tí wọ́n bá sì gbọ́ lè sún wọn láti wá dara pọ̀ mọ́ wa nínú bíbọlá fún Jèhófà.

7 Má ṣe fojú kéré ipa tí ayẹyẹ náà lè ní lórí wọn. Ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ yunifásítì kan sọ nìyí, ó ní: “Mo ti lọ síbi tí wọ́n ti ń gba Ara Olúwa nínú ṣọ́ọ̀ṣì mi lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ eléyìí yàtọ̀. Mo rí i pé èyí rí bí Bíbélì ṣe sọ ọ́ gan-an, mo sì rò pé ẹ̀yin ló ní òtítọ́.” Ó bẹ̀rẹ̀ sí wá sí ìpàdé déédéé, kò sì pẹ́ tó fi ṣèrìbọmi.

8 Ran Àwọn Ẹni Tuntun Lọ́wọ́ Láti Tẹ̀ Síwájú: Ṣàkíyèsí àwọn ẹni tuntun tó bá wá sí Ìṣe Ìrántí, kí o sì bẹ̀ wọ́n wò láìpẹ́ lẹ́yìn náà láti ṣàtúnyẹ̀wò àwọn nǹkan alárinrin tí wọ́n rí kọ́ tí wọ́n sì kíyè sí. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa àwọn ìpàdé yòókù, níbi tí wọ́n ti lè gba ìmọ̀ kún ìmọ̀ Bíbélì tí wọ́n ti ní. Ṣíṣàyẹ̀wò orí 17 nínú ìwé Ìmọ̀, tó sọ pé, “Rí Ààbò Láàárín Àwọn Ènìyàn Ọlọ́run,” yóò jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀pọ̀ yanturu ohun tẹ̀mí tí ìjọ ń pèsè, táwọn náà sì lè gbádùn wọn dáadáa. Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ṣètò fún wọn láti wo fídíò náà, Our Whole Association of Brothers, kí wọ́n lè fojú wọn rí ìṣọ̀kan, ayọ̀, àti ìtara tí àwọn èèyàn Jèhófà ní!

9 Ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn olùfìfẹ́hàn kọ́ bí olúkúlùkù wọn ṣe lè máa bọlá fún Jèhófà, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Ṣàlàyé pé àdúrà àtọkànwá máa ń mú inú Jèhófà dùn, ó sì jẹ́ orísun ìtura tẹ̀mí nígbà gbogbo. (1 Jòh. 5:14) Nípa lílo ẹ̀kọ́ 8 sí 12 nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, ṣàpèjúwe irú ìwà tó ń bọlá fún Jèhófà. Nípa jíjíròrò ohun tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ojú ìwé 30 àti 31, fún àwọn ẹni tuntun níṣìírí láti ronú lórí bí ó ṣe lè ṣeé ṣe fún wọn láti máa bọlá fún Jèhófà nípa kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù.

10 Ìmọrírì fún ẹbọ tí Jésù fi ara rẹ̀ rú àti fún àǹfààní táa ní láti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń bọlá fún Baba, ó sì ń mú ìbùkún wá bá àwọn ẹlòmíràn. Jésù ṣèlérí pé: “Bí ẹnikẹ́ni yóò bá ṣèránṣẹ́ fún mi, Baba yóò bọlá fún un.”—Jòh. 12:26.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́