“Lọ́dọ̀ Ọlọ́run Ohun Gbogbo Ṣeé Ṣe”
1 Wíwàásù ìhìn Ìjọba náà kárí ayé ni lájorí iṣẹ́ ìjọ Kristẹni. (Mát. 24:14) Iṣẹ́ takuntakun ni. Lójú ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wò wá, wọ́n wò ó pé agbára táa ní kò tóó ṣe iṣẹ́ ọ̀hún. Àwọn mìíràn sì ń ronú pé ó ṣòroó gbà gbọ́ pé a óò lè ṣe iṣẹ́ yìí nítorí pé àwọn èèyàn máa ń fi wá ṣẹlẹ́yà, wọ́n máa ń takò wá, wọ́n sì máa ń ṣenúnibíni sí wa. (Mát. 24:9; 2 Tím. 3:12) Àwọn oníyèmejì gbà pé iṣẹ́ yìí kò ní ṣeé ṣe. Ṣùgbọ́n, Jésù wí pé: “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.”—Mát. 19:26.
2 Àwọn Àpẹẹrẹ Rere Tó Yẹ Ká Fara Wé: Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, òun nìkan ló dojú kọ gbogbo ayé. Láti dí i lọ́wọ́ kó má lè ṣàṣeyọrí, àwọn alátakò tàbùkù rẹ̀ débi tó kọjá àfẹnusọ, wọ́n sì fikú oró pa á níkẹyìn. Síbẹ̀, lópin rẹ̀, Jésù fi ìgboyà polongo pé: “Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòh. 16:33) Ohun tó ṣe yìí mà kàmàmà o!
3 Irú ẹ̀mí ìgboyà àti ìtara yìí náà làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi hàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Wọ́n na ọ̀pọ̀ lọ́rẹ́, wọ́n lù wọ́n, wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n, àní wọ́n pa àwọn mìíràn. Síbẹ̀, ńṣe ni wọ́n “ń yọ̀ nítorí a ti kà wọ́n yẹ fún títàbùkù sí nítorí orúkọ rẹ̀.” (Ìṣe 5:41) Pẹ̀lú gbogbo ohun tó bá wọn yìí, wọ́n ṣe iṣẹ́ tó dà bíi pé kò lè ṣeé ṣe ti wíwàásù ìhìn rere náà “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8; Kól. 1:23.
4 Bí A Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Lọ́jọ́ Wa: Àwa pẹ̀lú ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tìtaratìtara lójú gbogbo ohun tó lè fẹ́ mú kó dà bíi pé kò ní ṣeé ṣe. Láìka ìfòfindè, inúnibíni, ìfisẹ́wọ̀n, àti àwọn ìgbésẹ̀ ìwà ipa mìíràn tí àwọn kan ń gbé láti dá wa dúró sí, a ń ṣe àṣeyọrí. Báwo lèyí ṣe ṣeé ṣe? “‘Kì í ṣe nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ológun, tàbí nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.” (Sek. 4:6) Bí Jèhófà ti wà lẹ́yìn wa, kò sóhun tó lè dá iṣẹ́ wa dúró!—Róòmù 8:31.
5 Nígbà táa bá ń wàásù, kò sídìí tó fi yẹ ká fòyà tàbí tó fi yẹ ká bẹ̀rù tàbí tó fi yẹ ká ronú pé a ò tóótun. (2 Kọ́r. 2:16, 17) Àwọn ìdí pàtàkì wà táa fi ní láti máa tẹ̀ síwájú ní títan ìhìn rere Ìjọba náà kálẹ̀. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, a ó ṣàṣeparí “ohun tí kò ṣeé ṣe”!—Lúùkù 18:27.