Jẹ́rìí Gẹ́gẹ́ Bí Aládùúgbò Rere
1 Jésù sọ pé “kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mát. 22:39) Dájúdájú, o ń “ṣe ohun rere” sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ṣé o lè ṣe ju ti tẹ́lẹ̀ kí o jẹ́ kó kan àwọn èèyàn tó ń gbé nítòsí rẹ? (Gál. 6:10) Ní àwọn ọ̀nà wo?
2 Nípa Jíjẹ́ Kí Wọ́n Mọ Ẹni Tóo Jẹ́: Ǹjẹ́ àwọn aládùúgbò rẹ̀ mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́? Bí wọn kò bá mọ̀, èé ṣe tí o kò dé ọ̀dọ̀ wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá? Àbájáde rẹ̀ lè yà ọ́ lẹ́nu! Tàbí kẹ̀, o lè jẹ́rìí fún wọn lọ́nà tí kò jẹ́ bí àṣà bó bá jẹ́ ìyẹn ni yóò túbọ̀ rọrùn fún ọ. Nígbà tóo bá jáde, o lè rí wọn tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ láyìíká ilé wọn tàbí tí wọ́n ń rìn gbafẹ́ lọ ní òpópónà. Sún mọ́ wọn, kí o sì rẹ́rìn-ín músẹ́. Sakun láti sọ fún wọn nípa àwọn ohun tí o gbà gbọ́, ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà, àti ohun tí a máa ń ṣe níbẹ̀, kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa àwọn mìíràn ní àdúgbò yín tó máa ń lọ síbẹ̀. Ké sí wọn wá sí ìpàdé. Múra tán láti jẹ́rìí kúnnákúnná nípa ìhìn rere fún gbogbo èèyàn tí o bá mọ̀.—Ìṣe 10:42; 28:23.
3 Nípa Ìwà Rẹ Tó Jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ: Ìwà ọ̀rẹ́ tí o ń hù máa ń sọ ohun púpọ̀ nípa rẹ, ó sì lè fún ọ láǹfààní láti jẹ́rìí. Ó tún máa ń ‘ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọ́run lọ́ṣọ̀ọ́.’ (Títù 2:7, 10) Ní ojúlówó ìfẹ́ fún àwọn aládùúgbò rẹ. Máa kó àwọn èèyàn mọ́ra, kí o sì máa lóye wọn. Má ṣe tojú bọ ọ̀ràn ìkọ̀kọ̀ wọn, má sì ṣe fariwo dí wọn lọ́wọ́. Bí ara ẹnì kan kò bá yá nínú wọn, fi ìgbatẹnirò hàn, kí o sì yọ̀ǹda láti ṣèrànwọ́. Nígbà tí ìdílé tuntun kan bá kó dé àdúgbò rẹ, ya ibẹ̀ láti kí wọn káàbọ̀. Irú ìwà inúure bẹ́ẹ̀ máa ń wúni lórí, ó sì ń mú inú Jèhófà dùn.—Héb. 13:16.
4 Nípa Ìrísí Ilé Rẹ: Jíjẹ́ aládùúgbò rere kan títọ́jú ilé rẹ kí ó lè dùn-ún wò. Ilé kan àti àyíká ilé tí ó mọ́ tó sì fani mọ́ra máa ń fúnra wọn jẹ́rìí. Ṣùgbọ́n àfàìmọ̀ kí ilé tó dọ̀tí tàbí tí àwọn àjákù nǹkan wà káàkiri ilẹ̀ rẹ̀ má tàbùkù ìhìn Ìjọba náà. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí o mú kí ilé rẹ, àyíká rẹ, àti ọkọ̀ rẹ wà ní mímọ́ kí o sì tún wọn ṣe dáadáa.
5 Ṣíṣàníyàn nípa àwọn tí kò sí nínú ìjọ Kristẹni ń fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò rẹ. Kí ló lè jẹ́ àbájáde rẹ̀? Ó ṣeé ṣe gan-an pé ‘nítorí àwọn iṣẹ́ rẹ àtàtà tí wọ́n fojú rí,’ díẹ̀ lára wọn yóò “yin Ọlọ́run lógo.”—1 Pét. 2:12.