ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/01 ojú ìwé 1
  • Kópa Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ Nínú Ìkórè Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kópa Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ Nínú Ìkórè Náà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Pápá Ti Funfun fún Kíkórè
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Ẹ Jẹ́ Òṣìṣẹ́ Tí Ń fi Tayọ̀tayọ̀ Kórè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ẹ Máa Bá Iṣẹ́ Ìkórè Náà Lọ Ní Rabidun!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Máa Kó Ipa Tó Jọjú Nínú Ìkórè Tẹ̀mí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 5/01 ojú ìwé 1

Kópa Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ Nínú Ìkórè Náà

1 Àwọn wòlíì Jèhófà ìgbà àtijọ́ àti Jésù Kristi alára sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìkójọpọ̀ kan. (Aísá. 56:8; Ìsík. 34:11; Jòh. 10:16) Irú iṣẹ́ yẹn la ń mú ṣe báyìí bí a ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà kárí ayé. (Mát. 24:14) Ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn tó ń sin Ọlọ́run àti àwọn tí kò sìn ín túbọ̀ ń fara hàn gbangba-gbàǹgbà. (Mál. 3:18) Kí nìyẹn túmọ̀ sí fún wa?

2 Ẹrù Iṣẹ́ Kan fún Olúkúlùkù: A lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù tó kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ní mímú ipò iwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Ó wò ó pé ó jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe fún òun láti wàásù kí gbogbo èèyàn lè ní àǹfààní láti gbọ́ nípa ìhìn rere kí wọ́n sì ní ìgbàlà. Èyí ló mú kí ó ṣiṣẹ́ láìdábọ̀ nítorí wọn. (Róòmù 1:14-17) Nítorí ipò eléwu tó ń kojú aráyé lónìí, a kò ha ní ẹrù iṣẹ́ tí ó túbọ̀ ga ti pé ká wàásù fún àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ táa yàn fún wa?—1 Kọ́r. 9:16.

3 Àkókò Tó Yẹ Láti Gbé Ìgbésẹ̀ Kánjúkánjú: A lè fi iṣẹ́ ìwàásù wé iṣẹ́ wíwá àwọn tó wà nínú ewu rí kí a sì gbà wọ́n là. A gbọ́dọ̀ wá àwọn èèyàn rí kí a sì mú wọn dé ibi ààbò kí ó tó pẹ́ jù. Àkókò kò fi bẹ́ẹ̀ sí mọ́. Ẹ̀mí wà nínú ewu! Abájọ tí Jésù fi rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.”—Mát. 9:38.

4 Bí ọ̀pọ̀ akéde Ìjọba Ọlọ́run ti rí i pé ọ̀ràn òde òní jẹ́ kánjúkánjú, wọ́n mú kí ipa tí wọ́n ń kó nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí túbọ̀ pọ̀ sí i. Ọ̀dọ́langba kan tó ń jẹ́ Hirohisa àti àwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́rin ń gbé lọ́dọ̀ ìyá wọn tó jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ. Ó máa ń rí owó láti ṣèrànwọ́ fún ìdílé rẹ̀ nípa jíjí ní aago mẹ́ta òru láti lọ ta ìwé ìròyìn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Hirohisa fẹ́ ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, nítorí náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé. Ǹjẹ́ ọ̀nà wà tí o lè gbà láti túbọ̀ kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ tí a kì yóò tún ṣe lẹ́ẹ̀kan sí i mọ́ yìí?

5 “Àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù.” (1 Kọ́r. 7:29) Nítorí náà, kí a ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe nínú iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ yìí tí a ń ṣe lórí ilẹ̀ ayé lónìí, ìyẹn ni wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Jésù fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí wé iṣẹ́ ìkórè. (Mát. 9:35-38) Bí a bá ń kópa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nínú ìkórè náà, èso iṣẹ́ wa lè jẹ́ pé a óò ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti di ara ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn olùjọsìn tí a ṣàpèjúwe ní Ìṣípayá 7:9, 10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́