Ẹ Máa Bá A Lọ Ní “Ṣíṣe Ohun Tí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀”
1 Ohun tó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ ni o ṣe nígbà tóo di ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ní báyìí, ìpèníjà táa ní ní àwọn àkókò lílekoko wọ̀nyí ni láti máa bá a lọ ní “ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.” (Gál. 6:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìsapá gidi lèyí gbà, o lè ṣe é. Báwo lo ṣe lè ṣe é?
2 Kọ́ Láti Ní Ẹ̀mí Èrò Orí Jésù: Bí Jésù ti ṣe, o lè fara da àwọn àdánwò bí o bá pọkàn pọ̀ sórí ìrètí Ìjọba náà. (Héb. 12:2, 3) Jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé Jèhófà fẹ́ràn rẹ, ó sì fẹ́ kí o ṣàṣeyọrí. (2 Pét. 3:9) Gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá, pẹ̀lú ìdánilójú pé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́. (1 Kọ́r. 10:13) Máa ní ìforítì nínú àdúrà, kí o sọ pé kí Jèhófà ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fara dà á. (Róòmù 12:12) Máa yọ̀ nítorí ìdánilójú tí o ní pé ìfaradà rẹ yóò yọrí sí ipò ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (Róòmù 5:3-5) Ìṣòtítọ́ rẹ nínú kíkọ́ “ẹ̀mí ìrònú kan náà tí Kristi Jésù ní” yóò fún ìwọ alára láyọ̀, yóò sì máa mú ọkàn Jèhófà yọ̀.—Róòmù 15:5; Òwe 27:11.
3 Máa Bá A Lọ Láti Ṣe Ohun Tó Tọ́: Lo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àǹfààní àwọn ohun tí Jèhófà pèsè fún àwọn èèyàn rẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bá a lọ láti ṣe ohun tó dára lọ́pọ̀lọpọ̀. Sọ ọ́ di àṣà láti máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé kí o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtẹ̀jáde ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye náà tí wọ́n gbé karí Bíbélì. Máa fi ìdúróṣinṣin múra sílẹ̀ fún gbogbo ìpàdé ìjọ, máa lọ sí àwọn ìpàdé wọ̀nyẹn, kí o sì máa kópa nínú wọn. Ṣáájú àti lẹ́yìn àwọn ìpàdé Kristẹni, kẹ́gbẹ́ pọ̀ dáadáa pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ nípa tẹ̀mí. Gbé àwọn góńgó tó bọ́gbọ́n mu kalẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ kí o lè kópa tó nítumọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá kí o sì lè mú kí òye rẹ nípa bí a ṣe ń sọ ìhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn túbọ̀ pọ̀ sí i.
4 Bí o ṣe lè máa bá a lọ láti ṣe ohun tó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ nìyí kí o sì tún máa láyọ̀ púpọ̀. Ní ti èyí, arákùnrin kan ní Ítálì sọ pé: “Nígbà tí mo bá darí sílé nírọ̀lẹ́ lẹ́yìn ọjọ́ kan nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, yóò ti rẹ̀ mí lóòótọ́. Ṣùgbọ́n mo máa ń láyọ̀ mo sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó ń fún mi ní ayọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbà lọ́wọ́ mi.” Nítorí náà, máa bá a lọ ní ṣíṣe ohun tó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, ìwọ pẹ̀lú yóò sì ní ayọ̀ ńláǹlà.