Dé Inú Ọkàn Akẹ́kọ̀ọ́ Rẹ
1 Ṣáájú kí Jésù to gòkè re ọ̀run, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n kọ́ àwọn ẹlòmíràn láti “máa pa” gbogbo ohun tí òun ti pa láṣẹ “mọ́.” (Mát. 28:19, 20) Bí ẹnì kan yóò bá “máa pa” àwọn àṣẹ Kristi “mọ́,” ìsọfúnni ọ̀hún gbọ́dọ̀ dé inú ọkàn rẹ̀. (Sm. 119:112) Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí ìsọfúnni náà dé inú ọkàn ẹni tí ò ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
2 Gbàdúrà fún Ìtọ́sọ́nà Jèhófà: Sísọni di ọmọ ẹ̀yìn jẹ́ iṣẹ́ Ọlọ́run. Ìbùkún rẹ̀ ló lè mú àṣeyọrí wá, kì í ṣe agbára tiwa. (Ìṣe 16:14; 1 Kọ́r. 3:7) Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé kí á máa gbàdúrà fún ìrànwọ́ Jèhófà láti lè fi òtítọ́ kọ́ àwọn ẹlòmíràn.—Aísá. 50:4.
3 Fòye Mọ Ohun Tí Akẹ́kọ̀ọ́ Náà Gbà Gbọ́: Mímọ ohun tí àwọn èèyàn gbà gbọ́ àti ìdí tí wọ́n fi gbà gbọ́ lè jẹ́ ká lóye ohun tí a lè sọ láti dé ọkàn wọn. Kí nìdí tí ẹ̀kọ́ kan ní pàtó fi fa akẹ́kọ̀ọ́ kan mọ́ra? Kí ló jẹ́ kí ó dá a lójú pé ó ṣeé gbà gbọ́? Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ká fi ìfòyemọ̀ sọ̀rọ̀.—Ìṣe 17:22, 23.
4 Ṣe Àlàyé Tó Bọ́gbọ́n Mu, Tó sì Bá Ìwé Mímọ́ Mu: Òtítọ́ gbọ́dọ̀ nítumọ̀ sí akẹ́kọ̀ọ́. (Ìṣe 17:24-31) A gbọ́dọ̀ ṣàlàyé ìdí tó yè kooro tó wà fún ìrètí wa. (1 Pét. 3:15) Ṣùgbọ́n, pẹ̀lẹ́tù àti sùúrù ni kí o máa fi ṣe èyí nígbà gbogbo.
5 Fi Àpèjúwe Kún Un: Yàtọ̀ sí pé àwọn àpèjúwe máa ń jẹ́ kí òye túbọ̀ tètè yé akẹ́kọ̀ọ́, wọ́n tún máa ń runi sókè. Wọ́n máa ń ní ipa lórí èrò inú àti ọkàn. Jésù lò wọ́n lọ́pọ̀ ìgbà. (Máàkù 4:33, 34) Àmọ́ ṣá o, kí àpèjúwe tí o lò tó lè gbéṣẹ́, ó gbọ́dọ̀ bá kókó tí o ń jíròrò mu, ó sì gbọ́dọ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé akẹ́kọ̀ọ́ náà.
6 Sọ Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Títẹ́wọ́ Gba Òtítọ́: Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ mọ àwọn àǹfààní tó wà nínú fífi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò. Ran akẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́wọ́ kí ó lè mọ ọgbọ́n tó wà nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ní 2 Tímótì 3:14-17.
7 Má ṣe rẹ̀wẹ̀sì bí àwọn kan kò bá kọbi ara sí ohun tí o ń kọ́ wọn. Àwọn ọkàn kan máa n yigbì. (Mát. 13:15) Ṣùgbọ́n, àwọn kan máa ń di onígbàgbọ́. (Ìṣe 17:32-34) Ǹjẹ́ kí ìsapá rẹ láti mú kí ìhìn rere wọ inú ọkàn ran èèyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti tẹ́wọ́ gba ohun tí Jésù pa láṣẹ kí wọ́n sì “máa pa” á “mọ́.”