ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/01 ojú ìwé 1
  • Má Ṣe Lọ́ Tìkọ̀!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Ṣe Lọ́ Tìkọ̀!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Àwọn Tí Ń mú Ìhìn Rere Ohun Tí Ó Dára Jù Wá’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Bá A Ṣe Lè Borí Ìṣòro Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwáàsù Ilé-dé-Ilé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ǹjẹ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ Jẹ Jèhófà Lógún Lóòótọ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • “Láti Ilé dé Ilé”
    Kọrin sí Jèhófà
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 7/01 ojú ìwé 1

Má Ṣe Lọ́ Tìkọ̀!

1 Nígbà táa bá fẹ́ lọ wàásù láti ilé dé ilé, ó lè jẹ́ bí a ṣe máa jáde nílé lọ wàásù gan-an ni ìṣòro wa. Èrò pé a kò tóótun lè mú ká lọ́ tìkọ̀ láti jáde lọ láti sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ fún “gbogbo onírúurú ènìyàn.” (1 Tím. 2:4) Ṣùgbọ́n kò yẹ kí á lọ́ tìkọ̀ láti wàásù ìhìn rere náà. Kí nìdí tí kò fi yẹ?

2 Iṣẹ́ Jèhófà Ni: Jèhófà ti sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú Bíbélì. Nígbà tí a bá mú iṣẹ́ yìí tọ àwọn ẹlòmíràn lọ, èrò rẹ̀ la ń sọ fún wọn, kì í ṣe tiwa. (Róòmù 10:13-15) Nígbà táwọn kan bá kọ ìhìn Ìjọba náà, Jèhófà ni wọ́n ń kọ̀ ní ti gidi. Síbẹ̀, ìyẹn kò ní kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá wa. A ní ìgbọ́kànlé pé iṣẹ́ yìí yóò mú kí àwọn tó fẹ́ kí ipò ayé yìí yí padà tí ohun tí wọ́n ṣe aláìní nípa tẹ̀mí sì ń jẹ lọ́kàn gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ.—Ìsík. 9:4; Mát. 5:3, 6.

3 Jèhófà Ló Ń Fa Àwọn Èèyàn Mọ́ra: Ẹni tí kì í fetí sí wa tẹ́lẹ̀ ti lè wá máa fetí sí wa báyìí nítorí pé ipò nǹkan ti yí padà fún un tí ọkàn rẹ̀ sì ti wá rọ̀. Jèhófà lè wá fi ìfẹ́ inú rere rẹ̀ hàn sí ẹni náà kí ó sì ‘fà á mọ́ra.’ (Jòh. 6:44, 65) Nígbà tí èyí bá ṣẹlẹ̀, a ní láti múra tán, ká jẹ́ kí Jèhófà lò wá kí á sì tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà áńgẹ́lì láti wá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ kàn.—Ìṣí. 14:6.

4 Ọlọ́run Ń Fún Wa Ní Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀: Ẹ̀mí mímọ́ ló ń jẹ́ kí á lè sọ̀rọ̀ “pẹ̀lú àìṣojo nípasẹ̀ ọlá àṣẹ Jèhófà.” (Ìṣe 14:1-3) Bí a bá ń rántí pé a ní ìtìlẹyìn alágbára yìí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, a kò ní lọ́ tìkọ̀ láti sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ fún àwọn aládùúgbò wa, àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ kíláàsì wa, àwọn ìbátan wa, tàbí àwọn tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé tàbí ọlọ́lá.

5 Jésù Kọ́ Wa Bí A Ṣe Máa Ṣe É: Jésù lo àwọn ìbéèrè tí ń múni ronú jinlẹ̀, àwọn àpèjúwe tó sọ ojú abẹ níkòó, àti àwọn àlàyé Ìwé Mímọ́. Ó ṣàlàyé òtítọ́ lọ́nà tó rọrùn, tó ń fani mọ́ra, látinú ọkàn rẹ̀ wá. Ìwọ̀nyí náà ṣì ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbà ṣe é lónìí. (1 Kọ́r. 4:17) Àwọn ibi tí a ti ń wàásù lè yàtọ̀ síra, ṣùgbọ́n ìhìn Ìjọba tó lágbára yìí kò yí padà.

6 Àǹfààní ló jẹ́ fún wa pé Jèhófà ń lò wá láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ lọ́nà àkànṣe tí ó sì ṣe kókó. Ká má ṣe lọ́ tìkọ̀ o! Kí á jẹ́ onígboyà kí á sì jẹ́ kí Jèhófà “ṣí ilẹ̀kùn àsọjáde fún wa” ká lè sọ ìhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn.—Kól. 4:2-4.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́