Orin 103
“Láti Ilé dé Ilé”
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Nílé délé, lẹ́nu ọ̀nà,
La ńsọ̀rọ̀ Jèhófà.
Nínú oko, nílùú délùú,
La ńbọ́ àgùntàn Jáà.
Ìhìn rere Ìjọba yìí
Tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀,
Làwọn Kristẹn’ tèwe tàgbà
Ńwàásù kárí ayé.
2. Nílé délé, lẹ́nu ọ̀nà,
La ńkéde ìgbàlà.
Ó wà fáwọn tó bá ńké pe
Orúkọ Jèhófà.
Ṣé wọ́n máa lè pe orúkọ
Ẹni tí wọn kò mọ̀?
Orúkọ mímọ́ náà gbọ́dọ̀,
Wọnú ilé wọn lọ.
3. Lọ sí gbogbo ẹnu ọ̀nà
Kéde ìhìn rere.
Wọn yóò gbọ́ tàbí wọn yóò kọ̀,
Wọn yóò yàn fúnra wọn.
Ká ṣáà mẹ́nu kan Jèhófà
Àti òtítọ́ rẹ̀.
Báa ti ńlọ látilé délé,
Aó rí àgùntàn rẹ̀.
(Tún wo Ìṣe 2:21; Róòmù 10:14.)