Àwọn Ìbùkún Tó Ń Wá Látinú Fífi Ìmọrírì Hàn fún Ìfẹ́ Tí Jèhófà Ní sí Wa—Apá Kìíní
1 Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Ní tiwa, àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí [Jèhófà] ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòh. 4:19) Nígbà tí a bá ronú nípa gbogbo ohun tí Jèhófà ti pèsè fún wa, a ń sún wa láti fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún un. Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní ṣíṣe èyí nípa ṣíṣe ìgbọràn ní wíwàásù nípa orúkọ Ọlọ́run àti Ìjọba náà. (Jòh. 14:31) Yóò ṣàǹfààní bí a bá ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà mélòó kan tí a lè gbà fi ìmọrírì wa hàn fún ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa àti àwọn ìbùkún tó ń tibẹ̀ wá.
2 Lílọ Láti Ilé dé Ilé: Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà. Ìtọ́sọ́nà tó fún wọn mú kó ṣe kedere pé wọ́n lọ láti ilé dé ilé, tí wọ́n sì ń wàásù ìhìn rere náà. (Lúùkù 9:1-6; 10:1-7) Ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run àti sí aládùúgbò wa ni kò ní jẹ́ ká ṣíwọ́ lílọ láti ilé dé ilé àní bí a bá tilẹ̀ bá ìdágunlá àti àtakò pàdé. Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwa fúnra wa yóò jàǹfààní, nítorí ìgbàgbọ́ wa yóò túbọ̀ lágbára sí i, àwọn ohun tí a gbà gbọ́ yóò túbọ̀ dá wa lójú, àwọn ohun tá a ń retí yóò sì túbọ̀ máa mú inú wa dùn.
3 Bí a ti ń ṣe iṣẹ́ yìí lábẹ́ ìtọ́sọ́nà àwọn áńgẹ́lì, a ti rí ọ̀pọ̀ àwọn tí ebi òtítọ́ ń pa tí òùngbẹ rẹ̀ sì ń gbẹ. (Ìṣí. 14:6) A ti rí àwọn onílé ti wọ́n sọ pé àwọn ti ń gbàdúrà pé kí Ẹlẹ́rìí kan wá sẹ́nu ọ̀nà àwọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì àti ọmọ kékeré kan ń lọ láti ilé dé ilé ní erékùṣù Caribbean kan. Nígbà táwọn tó dàgbà sọ pé àwọn fẹ́ ṣíwọ́ lọ́jọ́ náà, ọmọ kékeré yẹn fúnra rẹ̀ lọ sí ilé tó tẹ̀ lé e, ó sì kanlẹ̀kùn. Ni ọlọ́mọge kan bá ṣílẹ̀kùn. Nígbà táwọn tó jẹ́ àgbà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n wá lọ bá obìnrin náà, wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀. Ó sọ pé kí wọ́n wọlé, ó sì ṣàlàyé pé ńṣe lòun ń gbàdúrà lọ́wọ́ pé kí Ọlọ́run rán àwọn Ẹlẹ́rìí sí òun láti kọ́ òun ní Bíbélì!
4 Jíjẹ́rìí ní Òpópónà: Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ó ṣòro láti bá àwọn èèyàn nílé ní àwọn àgbègbè kan, ìjẹ́rìí òpópónà jẹ́ ọ̀nà kan tó gbéṣẹ́ láti wàásù fáwọn èèyàn. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbé ní àwọn ilé tí a dáàbò bò gan-an tí a kò ní lè dé ibẹ̀ bí a bá ń lọ láti ilé dé ilé. Ṣùgbọ́n ìmọrírì tá a ní fún ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa yóò sún wa láti lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti tọ àwọn èèyàn lọ ká sì sọ ìhìn Ìjọba náà fún wọn, títí kan jíjẹ́rìí ní òpópónà.—Òwe 1:20, 21.
5 Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò: Níwọ̀n bí a ti ń wá àwọn tí “àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn,” ó yẹ kí á ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe láti pèsè ohun tí wọ́n ṣaláìní yẹn. (Mát. 5:3) Ìyẹn ń béèrè pé ká padà lọ bomi rin irúgbìn òtítọ́ tí a gbìn. (1 Kọ́r. 3:6-8) Arábìnrin kan ní Ọsirélíà fún obìnrin kan ní ìwé àṣàrò kúkúrú ṣùgbọ́n ó fẹ́ dà bíi pé obìnrin ọ̀hún kò fìfẹ́ hàn. Síbẹ̀, arábìnrin yẹn kò juwọ́ sílẹ̀, ó gbìyànjú láti tún dé ọ̀dọ̀ obìnrin yẹn. Nígbà tí arábìnrin wa dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó rí i pé lẹ́yìn ìgbà àkọ́kọ́ tí òun lọ sọ́dọ̀ obìnrin yẹn, ó ti lọ ra Bíbélì olówó iyebíye kan. Ni arábìnrin náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́!
6 Dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Èyí ló máa ń gbádùn mọ́ni jù lọ tó sì ń mérè wá jù lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Ìbùkún ńláǹlà mà ni o láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n mọ̀ nípa Jèhófà, láti rí i kí wọ́n ṣe ìyípadà ní ìgbésí ayé wọn láti wù ú, lẹ́yìn náà kí a rí i tí wọ́n di Kristẹni tó ṣe ìrìbọmi láti fi ìyàsímímọ́ wọn sí Ọlọ́run hàn!—1 Tẹs. 2:20; 3 Jòh. 4.
7 Nínú ìtẹ̀jáde tó ń bọ̀, a ó ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀nà mìíràn tí a ti gbà bù kún wa nítorí fífi ìmọrírì hàn fún ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa.