Àwọn Ìbùkún Tó Ń Wá Látinú Fífi Ìmọrírì Hàn fún Ìfẹ́ Tí Jèhófà Ní sí Wa—Apá Kejì
1 Nígbà tí a ń jíròrò kókó ọ̀rọ̀ yìí lóṣù tó kọjá nínú apá kìíní, a mẹ́nu kan ọ̀nà mẹ́rin tí a lè gbà fi ìmọrírì tá a ní fún ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa hàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. (1 Jòh. 4:9-11) Níhìn-ín a ó sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọ̀nà márùn-ún mìíràn láfikún sí i, tí a lè gbà ṣe èyí. Nígbà tí a bá nípìn-ín kíkún nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí, a óò rí ìbùkún gbà.
2 Ìjẹ́rìí Àìjẹ́-bí-Àṣà: Èyí jẹ́ ọ̀nà kan tó gbéṣẹ́ láti wá àwọn ènìyàn tó ń yán hànhàn fún òdodo ká sì fún wọn ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó dára láti ‘ra àkókò tí ó rọgbọ padà’ kí á sì jẹ́rìí ní gbogbo ìgbà àti fún gbogbo ẹni tá a bá bá pàdé. (Éfé. 5:16) A ní láti lo ìgboyà láti jẹ́rìí lọ́nà yìí. Bí a bá mọrírì ìfẹ́ Ọlọ́run tí a sì mọ ohun tí àwọn ènìyàn nílò, a óò jẹ́rìí ní gbogbo àkókò tó bá ṣí sílẹ̀.—2 Tím. 1:7, 8.
3 Arákùnrin míṣọ́nnárì kan ṣe àṣeyọrísírere látàrí pé ó bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tí wọ́n jọ wọ ọkọ̀ takisí. Ọkùnrin tí wọ́n jọ wọkọ̀ yìí fìfẹ́ hàn. Ìpadàbẹ̀wò bẹ̀rẹ̀, èyí sì yọrí sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọkùnrin náà wá sínú òtítọ́, ó sì tẹ̀ síwájú débi pé ó di alàgbà nínú ìjọ!
4 Lẹ́tà Kíkọ: Bí kò bá ṣeé ṣe fún wa láti wàásù láti ilé dé ilé nítorí àìlera ara tàbí nítorí ojú ọjọ́ tí kò bára dé, a lè kọ lẹ́tà. A ó fi lẹ́tà náà jẹ́rìí ní ṣókí fún àwọn ẹni tí a mọ̀ tàbí àwọn tó ti pàdánù ẹni tí wọ́n fẹ́ràn nínú ikú tàbí àwọn tá ò bá nílé nígbà tá a wàásù dé ilé wọn. A lè fi ọ̀kan lára àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú wa tí ó bágbà mu ránṣẹ́ pẹ̀lú lẹ́tà náà. Kí ìwé àṣàrò kúkúrú náà jẹ́ èyí tí ó ní ìsọfúnni tó fani mọ́ra látinú Bíbélì, tó sì lè fún ẹni tó bá gbà á ní ìṣírí láti fẹ́ẹ́ sọ tẹnu rẹ̀ bó bá ní àwọn ìbéèrè. Lo àdírẹ́sì ìfìwéránṣẹ́ tìrẹ tí o fi ń gba lẹ́tà tàbí ti Gbọ̀ngàn Ìjọba yín; jọ̀wọ́ má ṣe lo àdírẹ́sì ọ́fíìsì ẹ̀ka o.
5 Ìjẹ́rìí Orí Tẹlifóònù: Èyí jẹ́ ọ̀nà kan tó dára láti gbà bá àwọn ẹni tí kò sí nílé nígbà tí a ń wàásù láti ilé-dé-ilé sọ̀rọ̀. Bí a bá ń fi òye àti inú rere, pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìjáfáfá ṣe é, ó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn dáhùn padà lọ́nà tó dára gan-an. Àwọn àbá tó gbéṣẹ́ lórí bí a ṣe lè ṣàṣeyọrí gidigidi ni a pèsè nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù February 2001, ní ojú ewé 5 sí 6.
6 Nígbà tí arábìnrin kan ń lo tẹlifóònù láti wàásù, ó béèrè lọ́wọ́ obìnrin kan bóyá ó ti ronú jinlẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú tiẹ̀ àti ti àwọn ẹbí rẹ̀. Lobìnrin ọ̀hún bá dáhùn pé òun ti ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣàlàyé pé òun kàn máa ń dá jókòó sílé ni nítorí pé ìbànújẹ́ dorí òun kodò tí òun ò sì nírètí. Nígbà tó rí bí arábìnrin wa ṣe ṣàníyàn nípa rẹ̀ látọkànwá, èyí wú u lórí ló bá gbà láti pàdé arábìnrin wa lọ́jà kan tó wà nítòsí. Àbájáde rẹ̀ ni pé, wẹ́rẹ́ lobìnrin náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì!
7 Kíkí Àwọn Àlejò Káàbọ̀: Bí a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn aládùúgbò wa, a ó lè wà lójúfò láti kíyè sí àwọn àjèjì tó bá ṣèbẹ̀wò sí ibi tí a ti ń ṣèpàdé, ká sì kí wọn káàbọ̀ tọ̀yàyà tọ̀yàyà. (Róòmù 15:7) Ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àárín àwọn èèyàn tó ní ire tẹ̀mí wọn lọ́kàn ni wọ́n wà. Àníyàn àtọkànwá tí a ní, àti fífi tí a bá fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ wọ́n lè sún wọn láti tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ tí a bá fẹ́ fún wọn.
8 Ìwà Ọmọlúwàbí Wa: A ń ṣe òtítọ́ lọ́ṣọ̀ọ́ nípa ìwà àtàtà tí a bá ń hù. (Títù 2:10) Nígbà tí àwọn èèyàn ayé bá gbóríyìn fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Ọlọ́run ni wọ́n ń bọlá fún. (1 Pét. 2:12) Èyí pẹ̀lú lè ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í tọ ọ̀nà ìyè.
9 Èé ṣe tó ò fi gbé àwọn ọ̀nà márùn-ún wọ̀nyí tí o lè gbà fi ìmọrírì rẹ hàn fún ìfẹ́ ńláǹlà tí Jèhófà ní sí wa yẹ̀ wò kí o sì gbìyànjú wọn wò? (1 Jòh. 4:16) Bó o ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀.