ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/01 ojú ìwé 1
  • Múra Sílẹ̀ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà O!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Múra Sílẹ̀ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà O!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Óò Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Wòlíì Ayé Àtijọ́ Tó Jíṣẹ́ Tó Bóde Òní Mu
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
  • Ẹ Máa Bá A Lọ Láti Fojú Sọ́nà fún Jèhófà
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
  • Wòlíì Ọlọ́run Mú Ìmọ́lẹ̀ Wá fún Aráyé
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2001
km 7/01 ojú ìwé 1

Múra Sílẹ̀ Láti Kẹ́kọ̀ọ́ Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà O!

1 “Kí ó dá àwọn olóòótọ́ olùjọsìn lójú pé, Jèhófà . . . kò ní gbà kí ayé Sátánì fi ọjọ́ kan ṣoṣo ré kọjá ohun tó bá ìdájọ́ òdodo mu.” Gbólóhùn yìí mà fúnni níṣìírí o! Ibo la ti fa ọ̀rọ̀ yìí yọ? Inú ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní ni. Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà fún wa ní ìdí láti ronú lọ́nà tó ń múni lọ́kàn yọ̀ bẹ́ẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni o! Nínú ìwé Bíbélì yẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ̀rọ̀ ìgbàlà dún gbọnmọgbọnmọ. (Aísá. 25:9) Ìdí nìyẹn tí á fi jẹ́ ìṣírí ńláǹlà fún wa láti kẹ́kọ̀ọ́ apá yìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Ṣe a óò máa lọ gbádùn rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀? Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

2 Aísáyà 30:20 pe Jèhófà ní ‘Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá.’ Olúkúlùkù Kristẹni gbọ́dọ̀ máa fara balẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀ bí Jèhófà ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ nínú ojú ewé Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti nínú àwọn ìtẹ̀jáde tí ń ṣàlàyé Bíbélì tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè. (Mát. 24:45; Aísá. 48:17, 18) Bí ọ̀rọ̀ ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní ṣe rí gan-an nìyẹn. Báwo lo ṣe lè jàǹfààní dáadáa nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀?

3 Múra Tán Láti Kópa Níbẹ̀: Ya àkókò tó pọ̀ sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ sílẹ̀. Ka gbogbo ìpínrọ̀ tí a yàn. Ronú nípa gbogbo ìbéèrè tí a tẹ̀. Sàmì sí ìdáhùn nínú ìwé rẹ. Lẹ́tà tó dúdú ju àwọn yòókù lọ la fi kọ àwọn ẹsẹ tí a fà yọ látinú ìwé Aísáyà. Fara balẹ̀ kà wọ́n. Ní ti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yòókù tí a tọ́ka sí, kà wọ́n láti mọ bí wọ́n ṣe jẹ mọ́ ibi tí a óò kẹ́kọ̀ọ́. Ṣàṣàrò nípa ohun tí o ń kẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà, bá àwùjọ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ rẹ ṣàjọpín ohun tí o múra sílẹ̀.

4 Kí arákùnrin tó ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ran gbogbo àwọn tó wá lọ́wọ́ láti lo Bíbélì wọn dáadáa kí wọ́n sì mọ bí ibi tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ tí wúlò tó. Bó bá jẹ́ ìwọ ni wọ́n kọ́kọ́ pè láti dáhùn, dáhùn ní ṣókí lọ́nà tó ṣe tààràtà. Bí ẹnì kan bá ti dáhùn lọ́nà bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, o lè ṣàlàyé síwájú sí i nípa kókó tí ẹ ń jíròrò. Bóyá o lè sọ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì kan ṣe ṣètìlẹyìn fún ẹṣin ọ̀rọ̀ ibẹ̀. Gbìyànjú láti dáhùn ní ọ̀rọ̀ ara rẹ, kí o sì jẹ adùn tó ń bẹ nínú kíkópa nínú ìjíròrò náà.

5 Ẹ jẹ́ ká jọ fi ìtara ṣàyẹ̀wò ìhìn iyebíye tó wà nínú ìwé Aísáyà. Yóò fún wa níṣìírí láti máa fayọ̀ retí ìgbàlà Jèhófà látọjọ́ dé ọjọ́!—Aísá. 30:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́