A Óò Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
Ẹ óò láyọ̀ láti mọ̀ pé bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ October 6, 1997, a óò ṣàyẹ̀wò ìwé náà, Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Kò sí ẹni tí yóò fẹ́ láti pàdánù àǹfààní ìjùmọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìtọ́sọ́nà gbígbéṣẹ́ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu yìí fún ìgbésí ayé ìdílé tí ó láyọ̀. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà yóò fàyè gba ṣíṣàyẹ̀wò ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹsẹ Bíbélì tí ó wà nínú ìwé náà kínníkínní.
A óò jíròrò orí kìíní pátápátá ní ọ̀sẹ̀ àkọ́kọ́ tí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà bá bẹ̀rẹ̀, níwọ̀n bí kò ti fi bẹ́ẹ̀ ní àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a kò ṣàyọlò wọn. Nítorí ìdí kan náà, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a óò jíròrò orí 15. Ṣùgbọ́n gbogbo orí yòó kù ní a óò pín sí apá méjìméjì, tí a óò máa jíròrò nǹkan bí ìdajì orí kan ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Nípa báyìí, àkókò tí ó tó yóò wà láti ka gbogbo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí kí a sì jíròrò wọn títí kan fífara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìfisílò gbogbo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a ṣàyọlò nínú ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan.
Apá pàtàkì kan nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà yóò jẹ́ jíjíròrò àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú àpótí ẹ̀kọ́ ní ìparí orí kọ̀ọ̀kan. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ fi àkókò tí ó tó sílẹ̀ fún jíjíròrò àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí tí ó wà nínú àpótí náà.
A rọ àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ láti fún ìmúrasílẹ̀ wọn fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ní àfiyèsí àkànṣe kí wọ́n sì fún gbogbo àwọn tí a yàn sí àwùjọ wọn, títí kan àwọn ẹni tuntun, níṣìírí láti múra sílẹ̀ dáradára, kí wọ́n máa pésẹ̀ déédéé, kí wọ́n sì máa kópa nínú rẹ̀.—om-YR ojú ìwé 74 sí 76.