A Óò Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run
A ṣe ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà pé kí a lè máa fi bá àwọn ẹni tuntun ṣèkẹ́kọ̀ọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ka ìwé Ìmọ̀ tán. Kíkà tí a óò ka ìwé yìí ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ yóò mú ká lè lo ìwé náà lóde ẹ̀rí, á sì ràn wá lọ́wọ́ láti mú kí ìfẹ́ àti ìmọrírì tá a ní fún Jèhófà àti ètò àjọ rẹ̀ jinlẹ̀ sí i. Báwo la ṣe lè jàǹfààní ní kíkún látinú ẹ̀kọ́ tí a óò kọ́ nínú ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run?
Dídarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Náà: Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé odindi orí kan la ó máa kà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, kí àwọn alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ṣètò àkókò náà dáadáa. Kí wọ́n má ṣe lo àkókò jù lórí àwọn ìpínrọ̀ tá a fi nasẹ̀ àkòrí náà, kí a bàa lè lo àkókò tó pọ̀ tó lórí àwọn apá pàtàkì tó sábà máa ń wà níparí orí kọ̀ọ̀kan náà. Bí a bá sọ̀rọ̀ lórí àpótí àtúnyẹ̀wò ní ṣókí, á mú kí àwọn tó wá sípàdé náà lè rántí àwọn kókó pàtàkì tá a kọ́.
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì nínú àwọn orí tó wà nínú ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run tó ní àwọn ìbéèrè tó wà fún àṣàrò àti ìjíròrò tí a kọ síbi tó wọnú díẹ̀ ju ìpínrọ̀ lọ. Àpẹẹrẹ kan ni ti èyí tó wà lójú ìwé 48 àti 49. Kò pọn dandan kí á ka àwọn ìbéèrè náà nígbà tá a bá ń ka àwọn ìpínrọ̀. Nígbà tí alábòójútó bá ń béèrè àwọn ìbéèrè náà lọ́wọ́ àwùjọ, kí ó sọ pé kí a ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí ká sì ṣàlàyé rẹ̀ bí àkókò bá ṣe wà sí.
Ìmúrasílẹ̀: Ìmúrasílẹ̀ tó mọ́yánlórí fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ju ká kàn falà sídìí àwọn ìdáhùn lọ. Bí a bá ṣàṣàrò dáadáa lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà, kì í ṣe pé yóò mú ká lè múra ìdáhùn sílẹ̀ nìkan ni, àmọ́ ní pàtàkì, á mú ká lè múra ọkàn wa sílẹ̀ pẹ̀lú. (Ẹ́sírà 7:10) Gbogbo wa la lè fún ara wa níṣìírí tá a bá ń dáhùn nípàdé, tí ìdáhùn náà sì gùn mọ níwọ̀n.—Róòmù 1:11, 12.
Ẹ̀kọ́ tí a óò kọ́ nínú ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà, yóò sì mú ká lè ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè dára pọ̀ mọ́ wa láti jọ́sìn rẹ̀. (Sm. 95:6; Ják. 4:8) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa jàǹfààní ní kíkún látinú ìṣètò rere nípa tẹ̀mí yìí.