A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà Lọ́sẹ̀ January 6
1. Bẹ̀rẹ̀ lọ́sẹ̀ January 6, àǹfààní wo la máa ní láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
1 Jèhófà fẹ́ ká sún mọ́ òun. (Ják. 4:8) Ká lè sún mọ́ ọn, a máa bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Sún Mọ́ Jèhófà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ láti ọ̀sẹ̀ January 6. Ohun tá a sọ ní ojú ìwé àkọ́kọ́ nípa ìdí tá a fi ṣe ìwé náà ni pé: “Tí a bá ń fara balẹ̀ ronú nípa ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà fi àwọn ànímọ́ rẹ̀ hàn lọ́kọ̀ọ̀kan, tí à ń rí i bí Jésù Kristi ṣe ń gbé àwọn ànímọ́ yìí yọ láìkù síbì kan, tí a sì ń mọ ọ̀nà tí àwa pẹ̀lú lè gbà máa fi àwọn ànímọ́ náà hàn, a óò dẹni tó sún mọ́ Ọlọ́run.” A ti ka ìwé yìí rí láàárín ọdún 2004 àti 2005 láwọn ìjọ. Àmọ́, lẹ́yìn ìgbà yẹn àwọn èèyàn bíi mílíọ̀nù méjì ló ti wá sínú òtítọ́, tí wọ́n sì di akéde Ìjọba Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa àwọn ìwà tó fani mọ́ra tí Jèhófà ní. Àwọn tí wọ́n sì ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé yìí tẹ́lẹ̀ máa túbọ̀ mọyì àwọn ìwà Jèhófà dáadáa bí wọ́n ṣe tún ń ka ìwé yìí lẹ́ẹ̀kan sí i.—Sm. 119:14.
2. Báwo la ṣe máa kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Sún Mọ́ Jèhófà?
2 Bí A Ṣe Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Náà: Ẹni tó máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà á fi ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣókí bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, bóyá bíi gbólóhùn kan tàbí méjì. A kò kọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbọ́dọ̀ kà sínú ìwé náà, torí náà olùdarí ló máa yan àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó gbé kókó tá à ń jíròrò yọ tó fẹ́ kà nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. A lè lo ìbéèrè kan tàbí méjì láti fi ṣe àtúnyẹ̀wò lẹ́yìn ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan. Tí ẹ̀kọ́ náà bá ní àpótí tá a pè ní “Ìbéèrè Tí A Ó Fi Ṣàṣàrò,” ẹ lò ó láti fi ṣe àtúnyẹ̀wò. Bí àkókò bá ṣe wà sí, kí ẹni tó bá darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ka àwọn kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí nínú àpótí náà, kí ó sì béèrè àwọn àfikún ìbéèrè kí àwọn ará lè sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀.
3. Bí a ṣe ń gbé ìwé náà yẹ̀ wò, kí ló yẹ ká ṣe, kí sì nìdí?
3 Jàǹfààní Lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́: Múra ibi tá a máa kà sílẹ̀ kódà bó bá jẹ́ pé o ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà rí. Gbìyànjú kó o dáhùn, torí èyí máa mú ìyìn bá Jèhófà, ó máa jẹ́ kó o rántí ohun tó o kọ́, ó sì máa ṣe àwọn míì láǹfààní. (Sm. 35:18; Héb. 10:24, 25) Bó o ṣe ń ronú nípa àwọn ìwà Jèhófà tí kò lẹ́gbẹ́, wàá túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Sm. 77:11-13) Èyí sì máa mú kí ìpinnu tó o ṣe pé wàá máa ṣègbọràn sí i túbọ̀ lágbára sí i, á sì máa wù ẹ́ láti sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíì.—Sm. 150:1-6.