Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ December 23
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ DECEMBER 23
Orin 127 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jl Ẹ̀kọ́ 23 sí 25 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ìṣípayá 7-14 (10 min.)
No. 1: Ìṣípayá 9:1-21 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Bí Àwa Kristẹni Ṣe Lè Fi Hàn Pé A Ní Ẹ̀mí Aájò Àlejò—Héb. 13:2 (5 min.)
No. 3: Èṣù Ni Ẹni Tí A Kò Lè Rí Tó Ń Ṣàkóso Ayé—td 10B (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù January àti February. Ìjíròrò. Sọ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé tá a máa lò, kó o sì ṣe àṣefihàn méjì.
20 min: “Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tá Ò Tíì Lè Fi Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣe àṣefihàn ọ̀kan lára àwọn àbá tó wà lójú ìwé 6.
Orin 46 àti Àdúrà