Orin 46
Jèhófà Ni Ọba Wa!
1. Ẹ yọ̀, ẹ fògo fún Jèhófà,
Torí ọ̀run ti sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀.
Jẹ́ ká fayọ̀ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run.
Ro ti iṣẹ́ àrà rẹ̀ gbogbo.
(ÈGBÈ)
Jẹ́ kí ọ̀run kó yọ̀, Kínú ayé sì dùn,
Torí Jèhófà di Ọba wa!
Jẹ́ kí ọ̀run kó yọ̀, Kínú ayé sì dùn,
Torí Jèhófà di Ọba wa!
2. Ròyìn ògo rẹ̀ fún aráyé;
Máa sọ̀rọ̀ ìgbàlà rẹ̀ lójoojúmọ́.
Ọba ni Jèhófà; tó yẹ kí a máa yìn.
A wólẹ̀ níwájú ìtẹ́ rẹ̀.
(ÈGBÈ)
Jẹ́ kí ọ̀run kó yọ̀, Kínú ayé sì dùn,
Torí Jèhófà di Ọba wa!
Jẹ́ kí ọ̀run kó yọ̀, Kínú ayé sì dùn,
Torí Jèhófà di Ọba wa!
3. Àkóso òdodo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀.
Ó gbé Jésù ọmọ rẹ̀ sórí ìtẹ́.
Kí ojú ti gbogbo òrìṣà ayé yìí,
Torí Ọlọ́run ni ìyìn yẹ.
(ÈGBÈ)
Jẹ́ kí ọ̀run kó yọ̀, Kínú ayé sì dùn,
Torí Jèhófà di Ọba wa!
Jẹ́ kí ọ̀run kó yọ̀, Kínú ayé sì dùn,
Torí Jèhófà di Ọba wa!
(Tún wo 1 Kíró. 16:9; Sm. 68:20; 97:6, 7.)