Orin 124
Gbà Wọ́n Pẹ̀lú Ẹ̀mí Aájò Àlejò
Bíi Ti Orí Ìwé
(Ìṣe 17:7)
1. Jèhófà láájò àlejò púpọ̀ gan-an.
Ó ńtọ́jú gbogbo wa láìku ẹnì kan.
Òjò òun oòrùn rẹ̀,
kìí dá ẹnì kan sí;
Ó ńbọ́ wa ó sì ńdùn wá nínú.
Nígbà táa bá ṣoore fáwọn aláìní,
Ọmọ Ọlọ́run tó fìwà jọọ́ ni wá.
Baba wa yóò sì san oore táa ṣe pa dà,
Tó bá jẹ́ pé ó tọkàn wa wá.
2. A kò mohun rere tó lè tibẹ̀ wá
Táa bá ṣoore fún àwọn aláìní.
Táa gbà wọ́n lálejò, bí wọ́n tiẹ̀ jájèjì,
Táa sì tọ́jú wọn dáradára.
Táa ṣe bíi Lìdíà táa gbà wọ́n sílé wa.
Tí wọ́n sinmi tára,
tù wọ́n nílé wa.
Kárí ayé, Baba wa ńrí gbogbo àwọn
Tó ńfara wée nínú ṣíṣàánú.
(Tún wo Ìṣe 16:14, 15; Róòmù 12:13; 1 Tím. 3:2; Héb. 13:2; 1 Pét. 4:9.)