Jàǹfààní Látinú Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà
1 Ní Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùfi Ìtara Pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run,” inú wa dùn gan-an láti gba ìwé náà, Sún Mọ́ Jèhófà. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn ará ti ka ìwé náà. Láìsí àní-àní, ohun tó túbọ̀ sún ọ̀pọ̀ jù lọ láti kà á ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2003: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Ják. 4:8.
2 Lóṣù March, a ó bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Sún Mọ́ Jèhófà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Báwo la ṣe lè jàǹfààní gan-an látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ wa? Ìmúrasílẹ̀ ṣe pàtàkì. Ọ̀sẹ̀ méjì ni yóò máa gbà wá láti kẹ́kọ̀ọ́ àkòrí kan, a ti ṣètò àwọn ìpínrọ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Èyí yóò fún ọ ní àkókò tó pọ̀ tó láti fi sọ ìdáhùn àtọkànwá rẹ tó o rí nígbà tó ò ń kẹ́kọ̀ọ́ tó o sì ń ṣàṣàrò lórí ìsọfúnni náà. Láfikún sí i, láwọn ọ̀sẹ̀ tá a bá máa kẹ́kọ̀ọ́ apá tó gbẹ̀yìn àkòrí kan, àwọn ìpínrọ̀ tá a máa jíròrò á tiẹ̀ tún kéré sí i, kí àkókò lè wà láti sọ̀rọ̀ lórí ohun pàtàkì kan tó wà nínú ìwé náà.
3Bẹ̀rẹ̀ láti àkòrí 2, àpótí kan tó ní àkọlé náà, “Ìbéèrè Tí A Ó Fi Ṣàṣàrò” ń fara hàn ní ìparí àkòrí kọ̀ọ̀kan. Kí alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ mú kí gbogbo àwùjọ gbé àpótí náà yẹ̀ wò lẹ́yìn tí a bá ti jíròrò ìpínrọ̀ tó gbẹ̀yìn nínú àkòrí kan. Kí ó mú kí àwọn ará sọ èrò ọkàn wọn jáde lórí ìsọfúnni náà, nípa mímú kí wọ́n sọ àwọn kókó pàtàkì tí wọ́n rí nígbà tí wọ́n ń ṣàṣàrò lórí Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. (Òwe 20:5) Láfikún sí àwọn ìbéèrè tí a béèrè nínú àpótí náà, ó tún lè béèrè irú àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí láwọn ìgbà míì: “Kí ni ìsọfúnni yìí ń jẹ́ kó o mọ̀ nípa Jèhófà? Báwo ló ṣe kan ìgbésí ayé rẹ? Báwo lo ṣe lè lò ó láti fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́?” Ńṣe ni kí ó sapá láti mú kí àwọn ará sọ ìdáhùn wọn látọkànwá, kì í ṣe pé kó máa béèrè àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tí kò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan lọ́wọ́ àwùjọ.
4 Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà kò lẹ́lẹ́gbẹ́ o. Lóòótọ́, gbogbo ìwé “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà ló ń fògo fún Jèhófà, àmọ́ ìdí pàtàkì tí a fi ṣe ìwé yìí ni láti fi ṣàlàyé àwọn ànímọ́ Jèhófà. (Mát. 24:45-47) Ẹ ò rí i pé àǹfààní ńláǹlà ló ń dúró dè wá! A ó jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ǹjẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Baba wa ọ̀run, kó sì tún ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ di ọ̀jáfáfá sí i nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti sún mọ́ ọn.